Read the New Testament in 24 Weeks
Paulu jẹ́ oníwàásù sí àwọn aláìkọlà
3 Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.
2 (A)Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; 3 bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí, 4 Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. 5 Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; 6 (B)pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìhìnrere.
7 Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. 8 Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; 9 (C)àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi: 10 Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, 11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa: 12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13 Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.
Àdúrà fún àwọn ará Efesu
14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.
20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.
Ìṣọ̀kan nínú ara Jesu
4 Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. 2 (D)Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. 3 Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà. 4 Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín. 5 Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan. 6 Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.
7 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi. 8 (E)Nítorí náà a wí pé:
“Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga,
ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn,
ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”
9 (Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? 10 Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) 11 Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. 12 Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi. 13 Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.
14 Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà; 15 (F)Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kristi. 16 (G)Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípasẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkára rẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.
Gbígbé ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀
17 Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. 18 Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn. 19 Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.
20 Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. 21 Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. 22 Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; 23 Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; 24 kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.
25 (H)Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. 26 Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín: 27 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. 28 Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.
29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. 30 Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. 31 Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn: 32 Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.