Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the New Testament in 24 Weeks

A reading plan that walks through the entire New Testament in 24 weeks of daily readings.
Duration: 168 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Heberu 1-2

Ọmọ tí o ṣe pàtàkì fún àwọn Angẹli

Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè. Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn.

(A)Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé:

“Ìwọ ni ọmọ mi;
    lónìí ni mo bí ọ”?

Àti pẹ̀lú pé;

“Èmi yóò jẹ́ baba fún un,
    Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”?

(B)Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,

“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”

(C)Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé;

“Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí,
    àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

(D)Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,

“Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni,
    ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.
Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;
nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi ààmì òróró ayọ̀ yàn ọ
    tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

10 Ó tún sọ pé,

“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,
    àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.
11 Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀
    gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.
12 Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,
    bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ̀ kì yóò yípadà
    àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”

13 (E)Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,

“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?

14 Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?

Ìkìlọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn

Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

Jesu bí arákùnrin rẹ̀

Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. (F)Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:

“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,
    tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ;
    ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,
    ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:
    Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”

Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

10 Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. 11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. 12 (G)Àti wí pé,

“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,
    ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”

13 (H)Àti pẹ̀lú,

“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”

Àti pẹ̀lú,

“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”

14 Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. 15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. 16 (I)Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún. 17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. 18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.