Read the New Testament in 24 Weeks
5 1 Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, 2 (A)ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.
3 Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; 4 Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. 5 Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. 6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. 7 Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.
8 Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: 9 (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). 10 Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. 11 Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. 12 Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. 13 Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. 14 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé,
“Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun,
sí jíǹde kúrò nínú òkú
Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”
15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16 (B)Ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19 (C)Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.
Àwọn aya àti ọkọ
21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
22 (D)Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. 23 Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. 24 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.
25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. 26 Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. 27 Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. 28 Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnrawọn. 29 Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. 30 Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. 31 (E)Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. 32 Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. 33 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Àwọn ọmọ àti àwọn òbí
6 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa: nítorí pé èyí ní ó tọ́. 2 (F)“Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí, 3 (G)“ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”
4 Àti ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa.
Àwọn ẹrú àti olówó wọn
5 Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, nínú òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kristi. 6 Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti inú ọkàn rẹ. 7 Ẹ máa fi gbogbo ọkàn yin ṣe iṣẹ́ ìsìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn. 8 Bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padà lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira.
9 Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.
Ìhámọ́ra Ọlọ́run
10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14 (H)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15 (I)Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. 19 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere náà. 20 Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.
Àwọn ìkíni ìkẹyìn
21 (J) Tikiku, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòtítọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mí mọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkan ti rí fún mí àti bí mo tí ń ṣe sí. 22 Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú.
23 Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jesu Kristi.
24 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi ni àìṣẹ̀tàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.