Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the New Testament in 24 Weeks

A reading plan that walks through the entire New Testament in 24 weeks of daily readings.
Duration: 168 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Matiu 14-15

A bẹ́ Johanu Onítẹ̀bọmi lórí

14 (A)Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”

(B)Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” (C)Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.

Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. 10 Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. 11 A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn

13 (D)Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. 14 Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.

15 Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”

16 Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

17 Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”

18 Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 19 (E)Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. 21 Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Jesu rìn lójú omi

22 (F)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn 23 Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, 24 (G)ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.

25 Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. 26 (H)Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.

27 Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

28 Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”

29 (I)Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”

Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. 30 Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”

31 (J)Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”

32 Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. 33 (K)Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”

34 (L)Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. 35 Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. 36 (M)Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

Ohun mímọ́ àti ohun àìmọ́

15 (N)Nígbà náà ní àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jesu wá láti Jerusalẹmu, wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín? Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;’ Tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

(O)“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,
    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.
Lásán ni ìsìn wọn;
    nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

10 Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín. 11 Ènìyàn kò di ‘aláìmọ́’ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ní di ‘aláìmọ́.’ ”

12 Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisi lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí?”

13 (P)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò, 14 Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

15 Peteru wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”

16 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”? 17 “Ẹyin kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde? 18 Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ 19 Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. 20 Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ ”

21 (Q)Jesu sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tire àti Sidoni. 22 Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”

23 Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24 (R)Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.”

25 (S)Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26 Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

27 Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”

28 (T)Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.

Jesu bọ́ ẹgbàajì ènìyàn

29 (U)Jesu ti ibẹ̀ lọ sí Òkun Galili. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀. 30 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúnkùn ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Òun sì mú gbogbo wọn láradá. 31 Ẹnu ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúnkùn ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Israẹli.

32 (V)(W) Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”

33 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ijù níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”

34 Jesu sì béèrè pé, “ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ní?”

Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìṣù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”

35 Jesu sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀. 36 Òun sì mú ìṣù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà. 37 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì ṣa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó ṣẹ́kù jẹ́ 38 Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé. 39 Lẹ́yìn náà, Jesu rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó rékọjá lọ sí ẹkùn Magadani.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.