Read the New Testament in 24 Weeks
Ìwé àti Ọ̀dọ́-àgùntàn
5 (A)Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí. 2 Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?” 3 Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀. 4 Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀. 5 (B)Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”
6 (C)Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo. 7 Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. 8 (D)Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́. 9 (E)Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:
“Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,
àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:
nítorí tí a tí pa ọ,
ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,
àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá:
10 (F)Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá:
wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”
11 (G)Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 12 Wọn ń wí lóhùn rara pé:
“Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa,
láti gba agbára,
àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,
àti ògo, àti ìbùkún.”
13 Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,
“Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,
fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn
náà láé àti láéláé.”
14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.
Ṣí àwọn èdìdì ìwé náà
6 Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!” 2 (H)Mo sì wò ó, kíyèsi i, ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọfà kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun.
3 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!” 4 Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.
5 Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. 6 (I)Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.
7 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó. 8 (J)Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.
9 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú: 10 (K)Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” 11 A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.
12 (L)Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13 (M)àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í. 14 A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.
15 (N)Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; 16 (O)Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà: 17 (P)Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé; ta ni sì le dúró?”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.