Read the New Testament in 24 Weeks
Ojúsàájú jẹ́ èèwọ̀
2 Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jesu Kristi, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. 2 Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; 3 tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” 4 ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?
5 Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? 6 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? 7 Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?
8 (A)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára. 9 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsàájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin. 10 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀. 11 (B)Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.
12 Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́. 13 Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.
Ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́
14 Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? 15 Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, 16 Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? 17 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.
18 Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:”
Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi. 19 Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.
20 Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? 21 (C)Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? 22 Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. 23 (D)Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 24 Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.
25 (E)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Rahabu panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn ayọ́lẹ̀wò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? 26 Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.
Kíkó ahọ́n ní ìjánu
3 Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù. 2 Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu.
3 Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. 4 Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. 5 Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! 6 Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà.
7 Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. 8 Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni.
9 Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. 10 Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. 11 Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? 12 Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù.
Oríṣìí ọgbọ́n méjì
13 Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15 Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16 Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.
17 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. 18 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.