Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

New Testament in a Year

Read the New Testament from start to finish, from Matthew to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Matiu 5:1-26

Ìwàásù orí òkè

(A)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.

Ó wí pé:

(B)“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí,
    nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
(C)Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,
    nítorí a ó tù wọ́n nínú.
(D)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,
    nítorí wọn yóò jogún ayé.
(E)Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa
    tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
Alábùkún fún ni àwọn aláàánú,
    nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
(F)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,
    nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
Alábùkún fún ni àwọn onílàjà,
    nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.
10 (G)Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,
    nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo
    nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

11 “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. 12 (H)Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀

13 (I)“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 (J)“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. 15 (K)Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.

Ìmúṣẹ òfin

17 “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. 18 (L)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 19 (M)Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. 20 Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Ìpànìyàn

21 (N)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ 22 Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.

23 “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. 24 Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.

25 (O)“Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú. 26 Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.