Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

New Testament in a Year

Read the New Testament from start to finish, from Matthew to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Johanu 11:1-29

Ikú Lasaru

11 (A)Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. (B)Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”

(C)Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”

(D)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”

(E)Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”

11 (F)Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”

12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” 13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.

14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú. 15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”

16 (G)Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”

Jesu tu àwọn arábìnrin rẹ̀ nínú

17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná, 18 Ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún: 19 (H)Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.

21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

24 (I)Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

25 (J)Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: 26 (K)Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

27 (L)Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.