New Testament in a Year
Bíbọ̀ ìjọba Ọlọ́run
20 (A)Nígbà tí àwọn Farisi bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú ààmì: 21 Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Kíyèsi i níhìn-ín!’ tàbí ‘Kíyèsi i lọ́hùn ún ni!’ sá à wò ó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.”
22 (B)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i. 23 (C)Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìn-ín;’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn. 24 (D)Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀. 25 (E)Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.
26 (F)“Bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn. 27 Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.
28 (G)“Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọti; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé; 29 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọti jáde kúrò ní Sodomu, òjò iná àti sulfuru rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.
30 “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ ènìyàn yóò farahàn. 31 (H)Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má ṣe sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn. 32 (I)Ẹ rántí aya Lọti. 33 (J)Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là. 34 (K)Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 35 Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 36 Ènìyàn méjì yóò wà ní oko, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”
37 (L)Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni igún ìkójọpọ̀ sí.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.