M’Cheyne Bible Reading Plan
Orin Debora
5 Nígbà náà ni Debora àti Baraki ọmọ Abinoamu kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé:
2 “Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli,
nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,
ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!
3 “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé!
Èmi yóò kọrin sí Olúwa,
Èmi yóò kọrin ìyìn sí Olúwa: Ọlọ́run Israẹli.
4 “Olúwa nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri,
nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu,
ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀,
àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀.
5 Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú Olúwa
Ọlọ́run Israẹli.
6 “Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati,
Ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá;
àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀.
7 Àwọn olórí tán ní Israẹli,
wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde
bí ìyá ní Israẹli.
8 Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun,
nígbà náà ni ogun wà ní ibodè
a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan
láàrín ẹgbàá ogun ní Israẹli bí.
9 Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli
àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn
Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!
10 “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,
ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára,
àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,
Ní ọ̀nà jíjìn sí 11 ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.
Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa,
àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli.
“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa
sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè.
12 ‘Jí, jí, Debora!
Jí, jí, kọ orin dìde!
Dìde ìwọ Baraki!
Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’
13 “Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ;
àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára.
14 Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki;
Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.
Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá,
láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.
15 Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora;
bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki,
wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.
Ní ipadò Reubeni
ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
16 Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn
láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn?
Ní ipadò Reubeni
ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
17 Gileadi dúró ní òkè odò Jordani.
Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi?
Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun,
ó sì ń gbé èbúté rẹ̀.
18 Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;
bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá.
19 “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;
àwọn ọba Kenaani jà
ní Taanaki ní etí odo Megido,
ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.
20 Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá
láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,
odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.
Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára!
22 Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,
nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.
23 ‘Ẹ fi Merosi bú’ ni angẹli Olúwa wí.
‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
láti dojúkọ àwọn alágbára.’
24 “Ìbùkún ni fún Jaeli,
aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́.
25 Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;
ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá.
26 Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,
ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,
òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,
ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin.
27 Ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀
ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀,
ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀;
níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí.
28 “Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé,
ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,
‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?
Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’
29 Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;
àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,
30 ‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi:
ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,
fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà,
ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,
àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,
gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’
31 (A)“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn,
nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”
Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.
Ìyípadà Saulu
9 (A)Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí-èémí ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ, 2 ó béèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí Sinagọgu tí ń bẹ ní ìlú Damasku pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbá à ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerusalẹmu. 3 Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súnmọ́ Damasku; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí i ká. 4 Ó sì ṣubú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Saulu, Saulu, èéṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”
5 Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?”
Olúwa sì wí pé, “Èmi ni Jesu, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí; (ohùn ìrora ni fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún). 6 Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe? Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”
7 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Saulu lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan. 8 Saulu sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Damasku. 9 Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.
10 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!”
Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”
11 Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà. 12 Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”
13 Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu. 14 Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”
15 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli. 16 Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”
17 Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” 18 Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.
Saulu ní Damasku àti Jerusalẹmu
Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀ 20 Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run. 21 Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.” 22 Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.
23 Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á 24 (B)Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. 25 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.
26 Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni. 27 Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. 28 Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. 29 Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a. 30 Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu.
31 Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.
Aenea àti Dọkasi
32 Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida. 33 Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà. 34 Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà. 35 Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.
36 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe. 37 Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè. 38 Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.”
39 Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà: gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.
40 Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. 41 Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè. 42 Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́. 43 Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.
Ní ilé amọ̀kòkò
18 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe: 2 “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” 3 Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́. 4 Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.
5 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 6 (A)“Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. 7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun. 8 Tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.
11 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’ 12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”
13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:
“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,
ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?
Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni
yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?
Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,
tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,
wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,
tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,
àti ọ̀nà wọn àtijọ́.
Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,
àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe
16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di
nǹkan ẹ̀gàn títí láé;
Gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,
wọn yóò sì mi orí wọn.
17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,
Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.
Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn
ní ọjọ́ àjálù wọn.”
18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”
19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun
tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
20 Ṣe kí a fi rere san búburú?
Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,
rántí pé mo dúró níwájú rẹ,
mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti
yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn
jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà
jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó
jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn
kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
wọn lójú ogun.
22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn
nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun
kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́
kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi
23 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ
gbogbo ète wọn láti pa mí,
má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.
Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.
Òwe afúnrúgbìn
4 (A)Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: 3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. 4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. 7 Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. 8 Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9 Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
10 (B)Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” 11 (C)Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. 12 (D)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,
“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”
13 (E)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? 14 Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. 15 Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. 16 Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 17 Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. 18 Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. 19 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. 20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
Àtùpà lórí ọ̀pá fìtílà
21 (F)Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òṣùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22 (G)Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23 (H)Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 (I)Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. 25 (J)Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”
Òwe irúgbìn tó ń dàgbà
26 (K)Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”
Òwe musitadi
30 (L)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (M)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
Jesu mú afẹ́fẹ́ okun dákẹ́ jẹ́ẹ́
35 (N)Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apá kejì.” 36 Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n sì gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 37 Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. 38 Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”
39 Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.
40 Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?”
41 Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti Òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.