M’Cheyne Bible Reading Plan
Olúwa kọ Saulu ní ọba
15 Samuẹli wí fún Saulu pé, “Èmi ni Olúwa rán láti fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli; fetísílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́. 2 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi yóò jẹ àwọn Amaleki ní yà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ejibiti. 3 Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọlu Amaleki, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tiwọn ní à parun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.’ ”
4 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Talaemu, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (200,000) àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárùn-ún àwọn ọkùnrin Juda (10,000). 5 Saulu sì lọ sí ìlú Amaleki ó sì gọ dè wọ́n ní Àfonífojì kan. 6 Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ará Keni pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Amaleki kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè ti Ejibiti wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kenaiti lọ kúrò láàrín àwọn Amaleki.
7 Nígbà náà ni Saulu kọlu àwọn Amaleki láti Hafila dé Ṣuri, tí ó fi dé ìlà-oòrùn Ejibiti. 8 Ó sì mú Agagi ọba Amaleki láààyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlù gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. 9 Ṣùgbọ́n Saulu àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ dá Agagi sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátápátá ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì níláárí ni wọ́n parun pátápátá.
10 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Samuẹli wá pé: 11 “Èmi káàánú gidigidi pé mo fi Saulu jẹ ọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Samuẹli sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì ké pe Olúwa ní gbogbo òru náà.
12 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Samuẹli sì dìde láti lọ pàdé Saulu, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Saulu ti wá sí Karmeli. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gilgali.”
13 Nígbà tí Samuẹli sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Saulu sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ.”
14 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?”
15 Saulu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ní o mú wọn láti Amaleki wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tókù run pátápátá.”
16 Samuẹli sí wí fún Saulu pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí Olúwa wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”
Saulu sì wí pé, “Sọ fún mi.”
17 Samuẹli sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Israẹli? Olúwa fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli. 18 Olúwa sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Amaleki run pátápátá; gbóguntì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ 19 Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti Olúwa? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú Olúwa?”
20 Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá. 21 Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.”
22 (A)Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé,
“Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ
ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́?
Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ,
ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.
23 Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ,
àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà.
Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,
Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”
24 Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́. 25 Mo bẹ̀ ọ́ nísinsin yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin Olúwa.”
26 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa sílẹ̀, Olúwa sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli!”
27 Bí Samuẹli sì ti fẹ́ yípadà láti lọ, Saulu sì di ẹ̀wù ìlekè rẹ̀ mú, ó sì fàya; 28 Samuẹli sì wí fún un pé, “Olúwa ti fa ìjọba Israẹli ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ. 29 Ẹni tí ó ń ṣe ògo Israẹli, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”
30 Saulu sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbàgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Israẹli, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.” 31 Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli sì yípadà pẹ̀lú Saulu, Saulu sì sin Olúwa.
32 Nígbà náà ni Samuẹli wí pé, “Mú Agagi ọba àwọn ará Amaleki wá fún mi.”
Agagi sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, “Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá.”
33 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé,
“Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ
bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàrín obìnrin.”
Samuẹli sì pa Agagi níwájú Olúwa ni Gilgali.
34 Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu. 35 Samuẹli kò sì padà wá mọ́ láti wo Saulu títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Samuẹli káàánú fún Saulu. Ó sì dun Olúwa pé ó fi Saulu jẹ ọba lórí Israẹli.
Ṣíṣe ìgbọ́ràn sí àwọn aláṣẹ
13 (A)Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá. 2 Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn. 3 (B)Nítorí àwọn ìjòyè kò wá láti dẹ́rùbà àwọn tí ń ṣe rere, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣe búburú. Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù ẹni tó wà ní ipò àṣẹ. Nítorí náà ṣe èyí tó ó dára, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 4 (C)Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni i ṣe fún ọ́ sí rere. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣé búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò gbé idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní í ṣe, olùgbẹ̀san láti ṣiṣẹ́ ìbínú lára ẹni tí ń ṣe búburú. 5 Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú.
6 Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo. 7 (D)Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀.
Ẹ jẹ gbèsè ìfẹ́
8 (E)Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. 9 (F)Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” 10 (G)Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé
11 (H)Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12 (I)Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13 (J)Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14 (K)Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Ìṣubú Jerusalẹmu
52 Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá. 2 (A)Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe 3 Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀.
Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.
4 Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀. 5 Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá ọba Sedekiah.
6 Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 7 Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ-ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrín odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Babeli yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ. 8 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ogun Babeli lépa ọba Sedekiah wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká. 9 Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn.
Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 10 Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda. 11 Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
12 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàn-dínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu. 13 Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńláńlá. 14 Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 15 Nebusaradani balógun ìṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 16 Ṣùgbọ́n Nebusaradani, balógun ìṣọ́ fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti ro oko.
17 Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli. 18 Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ. 19 Balógun ìṣọ́ náà kó àwokòtò wọ̀n-ọn-nì, ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti ago wáìnì wọ̀n-ọn-nì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.
20 Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ. 21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú. 22 Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra. 23 Pomegiranate mẹ́rìn-dínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan.
24 Balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ mu Seraiah olórí àwọn àlùfáà àti Sefaniah àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 25 Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà. 26 Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 27 Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati.
Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
28 Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.
Ní ọdún keje ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó-lé-mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda.
29 Ní ọdún kejì-dínlógún Nebukadnessari
o kó ẹgbẹ̀rún ó-lé-méjì-dínlọ́gbọ̀n láti Jerusalẹmu.
30 Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù
tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín-márùn-ún (745).
Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.
Ìtúsílẹ̀ Jehoiakimu
31 Ní ọdún kẹtà-dínlógójì ti Jehoiakini ọba Juda ni Efili-Merodaki di ọba Babeli. Ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù kejìlá. 32 Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. 33 Nítorí náà, Jehoiakini pàrọ̀ aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34 Ní ojoojúmọ́ ni ọba Babeli ń fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè, títí di ọjọ́ kú rẹ̀.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
gbà mí nínú òdodo rẹ.
2 Tẹ́ etí rẹ sí mi,
gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
3 Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
4 Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
5 Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
6 Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
7 Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi
ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
8 Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.
9 Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
egungun mi sì ti rún dànù.
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 (A)Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
láti gba ẹ̀mí mi.
14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa
Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
nítorí pé mo ké pè ọ́;
jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.
18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
kúrò nínú ìjà ahọ́n.
21 Olùbùkún ni Olúwa,
nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
“A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
Olúwa pa olódodo mọ́,
ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.