M’Cheyne Bible Reading Plan
24 Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari. 2 Olúwa sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì. 3 Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. 4 Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjì.
5 Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda? 6 Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
7 Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.
Jehoiakini ọba Juda
8 (A)Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjì-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu. 9 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.
10 Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, 11 Nebukadnessari ọba Babeli fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. 12 Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.
Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n. 13 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa. 14 Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárùn-ún ún, àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.
15 Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà. 16 Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli 17 Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.
Sedekiah ọba Juda
18 (B)Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó sì wá láti Libina. 19 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 20 Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.
Ìṣubú Jerusalẹmu
Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.
6 Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run, 2 ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. 3 Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.
4 Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, 5 tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, 6 láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba. 7 Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. 8 (A)Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná.
9 Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin: 12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.
Ìdánilójú ìlérí Ọlọ́run
13 (B)Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, 14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.” 15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.
16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀. 17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. 18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin: 19 (C)Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; 20 (D)níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
A dá orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́
3 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà,
nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.
2 Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ
pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí Àfonífojì Jehoṣafati.
Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,
àti nítorí Israẹli ìní mi,
tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè,
wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.
3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi;
wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,
wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún
ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.
4 (A)“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. 5 Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. 6 Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.
7 “Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. 8 Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.
9 Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;
Ẹ dira ogun,
ẹ jí àwọn alágbára,
Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun,
10 (B)Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,
àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.
Jẹ́ kí aláìlera wí pé,
“Ara mi le koko.”
11 Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,
kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.
Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.
12 “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí Àfonífojì
Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:
nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe
ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
13 Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,
nítorí ìkórè pọ́n:
ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀;
nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn
ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀
nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”
14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀
ní àfonífojì ìpinnu,
nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀
ní àfonífojì ìdájọ́.
15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,
àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
16 Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,
yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;
àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì
Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,
àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.
Ìbùkún fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run
17 “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,
tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi.
Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́;
àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.
18 “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,
àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa sàn fún wàrà;
gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi.
Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá,
yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.
19 Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro,
Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,
nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda,
ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,
àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.
21 Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.
Nítorí Olúwa ń gbé Sioni.”
Saamu ti Dafidi.
143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
fetísí igbe mi fún àánú;
nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
2 (A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
3 Ọ̀tá ń lépa mi,
ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.
7 Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.