Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 12-13

Miriamu Àti Aaroni tako Mose

12 Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia. Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.

(Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).

Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta. Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú, Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi:

“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín
    Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran,
    Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.
(A)Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi:
    ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi.
(B)Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,
    ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,
    ó rí àwòrán Olúwa
Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù
    láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”

Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.

10 Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀, 11 Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn. 12 Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”

13 Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!”

14 (C)Olúwa sì dá Mose lóhùn, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.” 15 Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà.

16 Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Haserotu, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Parani.

Ṣíṣe Ayọ́lẹ̀wò sí ilẹ̀ Kenaani

13 Olúwa sọ fún Mose pé, “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”

Mose sì rán wọn jáde láti Aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.

Orúkọ wọn nìwọ̀nyí:

láti inú ẹ̀yà Reubeni Ṣammua ọmọ Sakkuri;

láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;

láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne;

Láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu;

Láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni;

Láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu;

10 Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi;

11 Láti inú ẹ̀yà Manase, (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;

12 Láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;

13 Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

14 Láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;

15 Láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.

16 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)

17 Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè 18 Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19 Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi? 20 Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)

21 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati. 22 Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.) 23 Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24 Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀. 25 Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.

Ìròyìn nípa ilẹ̀ tí wọ́n yẹ̀ wò

26 Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí. 28 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀. 29 Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá Òkun àti ní etí bèbè Jordani.”

30 Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.”

31 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.” 32 Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀. 33 (D)A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”

Saamu 49

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
    Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
    tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
    èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
    Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
    tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
    padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
    kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
Ní ti kí ó máa wà títí ayé
    láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
    bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
    ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
    ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
    gbàgbọ́ nínú ara wọn,
àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
    tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú
    ikú yóò jẹun lórí wọn;
ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,
    jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀;
Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,
    isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
    kúrò nínú isà òkú,
yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
    Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
    ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú
18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
    Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
    àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Isaiah 2

Òkè Olúwa

Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu:

(A)Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́

òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ,
    gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
    àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
    kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
    àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,
    wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,
    ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.

Ọjọ́ Olúwa

Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
    ìwọ ilé Jakọbu.
Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,
    wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,
    wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.
Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
    ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
    kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,
    wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
    èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
    ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
    má ṣe dáríjì wọ́n.

10 Wọ inú àpáta lọ,
    fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
kúrò nínú ìpayà Olúwa,
    àti ògo ọláńlá rẹ̀!
11 Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀
    a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,
    Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́
    fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga
    nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),
13 nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó
    àti gbogbo óákù Baṣani,
14 nítorí gbogbo òkè gíga ńláńlá
    àti àwọn òkè kéékèèkéé,
15 fún ilé ìṣọ́ gíga gíga
    àti àwọn odi ìdáàbòbò,
16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò
    àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba
    a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀,
    Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.

19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta
    àti sínú ihò ilẹ̀
kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa
    àti ògo ọláńlá rẹ̀,
    nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ
    àwọn ère fàdákà àti ère wúrà
tí wọ́n ti yá fún bíbọ
    sí èkúté àti àwọn àdán,
21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta
    àti sínú ihò pàlàpálá àpáta
kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa
    àti ògo ọláńlá rẹ̀,
    nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

22 Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́,
    èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀.
Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?

Heberu 10

Ìrúbọ Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún gbogbo ènìyàn

10 Nítorí tí òfin jẹ́ òjìji àwọn ohun rere ti ń bọ̀ tí kì í ṣe àwòrán tòótọ́ fún àwọn òtítọ́ náà, wọn kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbà gbogbo lọ́dọọdún mu àwọn tí ń wá jọ́sìn di pípé. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún. Nítorí ko ṣe é ṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

(A)Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé,

“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,
    ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi;
Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni
    ìwọ kò ní inú dídùn sí.
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)
    mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀. 10 Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

11 Àti olúkúlùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé: 12 (B)Ṣùgbọ́n òun, lẹ́yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; 13 Láti ìgbà náà, ó retí títí a o fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀. 14 Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.

15 Ẹ̀mí Mímọ́ sì ń jẹ́rìí fún wa pẹ̀lú: Nítorí lẹ́yìn tí ó wí pé,

16 (C)“Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá
    lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.
Èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn,
    inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”

17 Ó tún sọ wí pé:

“Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn
    lèmi kì yóò sì rántí mọ́.”

18 Ṣùgbọ́n níbi tí ìmúkúrò ìwọ̀nyí bá gbé wà, ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́.

Ìpè sí ìforítì

19 Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jesu, 20 nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọjá aṣọ ìkélé èyí yìí ní, ara rẹ̀; 21 àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run; 22 ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù. 23 Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì; (nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí). 24 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere: 25 kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27 (D)Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 28 (E)Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: 29 (F)Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 30 (G)Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé: Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31 Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

32 Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; 33 lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. 34 Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. 35 Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.

36 Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. 37 (H)Nítorí,

“Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,
    ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé,
    kí yóò sì jáfara.

38 Ṣùgbọ́n,

“Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́.
    Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn,
    ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”

39 Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.