Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Historical

Read the books of the Bible as they were written historically, according to the estimated date of their writing.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 4-7

A ya àwòrán ìgbógunti Jerusalẹmu

“Nísinsin yìí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí rẹ̀. Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká. Kí o sì fi àwo irin kan ṣe ògiri láàrín rẹ̀ àti ìlú yìí, kí o sì kọjú sí i, a ó sì dó tì í, ìwọ yóò sì dó tì í. Èyí yóò jẹ́ ààmì fún ilé Israẹli.

“Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irínwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

“Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan. Ìwọ dojúkọ ìgbógunti Jerusalẹmu, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà. Èmi yóò dè ọ́ ní okùn dé bi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbóguntì rẹ yóò fi pé.

“Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irínwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá. 10 Wọn òṣùwọ̀n ogún ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀. 11 Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀. 12 Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà barle; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.” 13 Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

14 Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Olódùmarè! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsin yìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnrarẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”

15 Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn.”

16 Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jerusalẹmu. Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ jẹ pẹ̀lú ìfọkànsọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú, 17 nítorí pé oúnjẹ àti omi yóò wọ́n. Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú ìyanu, èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Idà n bọ̀ sórí Jerusalẹmu

“Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi ṣe abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in. Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdákan nínú ìdámẹ́ta irun yìí níná láàrín ìlú. Mú ìdákan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdákan yòókù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká. Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ. Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Israẹli.

“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká. Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́.

“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká lọ, tí ẹ kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ túnṣe dáradára tó àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká.

“Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jerusalẹmu, èmi yóò sì jẹ ọ́ ní yà lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká. Nítorí gbogbo ohun ìríra rẹ, èmi yóò ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrín rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́. 10 Nítorí náà láàrín rẹ àwọn baba yóò máa jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. Èmi yóò jẹ ọ́ ní yà, èmi yóò sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú ẹ̀fúùfù. 11 Nítorí náà, Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ṣe wà láààyè, nítorí pé ìwọ ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, èmi yóò mú ojúrere mi kúrò lára rẹ, èmi kò ní í da ọ sí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́. 12 Ìdámẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdámẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ, èmi yóò sì tú ìdámẹ́ta yòókù ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì máa fi idà lé wọn.

13 “Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbóná mi yóò sì rọlẹ̀, èmi yóò sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.

14 “Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá 15 O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ẹ̀kọ̀ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀. 16 Nígbà tí èmi ó rán ọfà búburú ìyàn sí wọn, èyí tí yóò jẹ́ fún ìparun wọn. Èmí tí èmi yóò rán run yín. Èmí yóò sì sọ ìyàn di púpọ̀ fún yín. Èmí yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ yín. 17 Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ̀ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò kọjá láàrín yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè Israẹli

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn òkè Israẹli; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn wí pé: ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèkéé, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí Àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run. Èmi yóò wó pẹpẹ yín lulẹ̀, èmi yóò sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn. Èmi yóò tẹ́ òkú àwọn ará Israẹli síwájú òrìṣà wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká. Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́. Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrín yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ṣùgbọ́n èmi yóò dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè. Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn. 10 Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé èmi yóò mú ìdààmú bá wọn.

11 “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” Ilé Israẹli yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn. 12 Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni èmi yóò ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn. 13 Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrín òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù, níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí olóòórùn dídùn rú ẹbọ sí gbogbo òrìṣà wọn. 14 Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò, kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Dibila—ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

Òpin ti dé

Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: (A)“Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli:

“ ‘Òpin! Òpin ti dé
    sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!
Òpin tí dé sí ọ báyìí,
    èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ,
èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ,
    èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.
Ojú mi kò ní i dá ọ sì,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú;
    ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
    àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ.

Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

“Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo
    Kíyèsi, ń bọ̀ ní orí rẹ;
Òpin ti dé!
    Òpin ti dé!
Ó ti dìde lòdì sí ọ.
    Kíyèsi, ó ti dé!
Ìparun ti dé sórí rẹ,
    ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà.
Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé!
    Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.
Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí
    àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ,
èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
    àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ.
Ojú mi kò ní i dá ọ sí,
    èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú;
èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
    àti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ.

Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi Olúwa lo kọlù yín.

10 “ ‘Ọjọ́ náà dé!
    Kíyèsi ó ti dé!
Ìparun ti bú jáde,
    ọ̀pá ti tanná,
    ìgbéraga ti rúdí!
11 Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú;
    ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà.
Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù,
    tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn,
kò sí nínú ọrọ̀ wọn,
    kò sí ohun tí ó ní iye.
12 Àkókò náà dé!
    Ọjọ́ náà ti dé!
Kí òǹrajà má ṣe yọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀;
    nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
13 Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà
    dúkìá èyí tó tà
    níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè.
    Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí
    kò ní yí padà.
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn
    tí yóò gba ara rẹ̀ là.

14 “ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun,
    tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun,
    nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.
15 Idà wà ní ìta,
    àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé,
idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè,
    àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
16 Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà,
    wọn yóò sì wà lórí òkè.
Bí i àdàbà inú Àfonífojì,
    gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀,
    olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.
17 Gbogbo ọwọ́ yóò rọ,
    gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.
18 Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀,
    ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,
ìtìjú yóò mù wọn,
    wọn yóò sì fá irun wọn.

19 “ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó,
    wúrà wọn yóò sì dàbí èérí
fàdákà àti wúrà wọn
    kò ní le gbà wọ́n
    ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa.
Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn
    tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ
    nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
20 Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà,
    wọn sì ti fi ṣe òrìṣà,
wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀.
    Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn.
21 Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì
    àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé,
    wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.
22 Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn,
    àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́;
àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀,
    wọn yóò sì bà á jẹ́.

23 “ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin!
    Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
    ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
24 Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ
    láti jogún ilé wọn.
Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára,
    ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.
25 Nígbà tí ìpayà bá dé,
    wọn yóò wá àlàáfíà, kì yóò sì ṣí
26 Wàhálà lórí wàhálà yóò dé,
    ìdágìrì lórí ìdágìrì.
Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì,
    ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà,
    bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.
27 Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,
    ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí,
    ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì.
Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn,
    èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn.

Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.