Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Historical

Read the books of the Bible as they were written historically, according to the estimated date of their writing.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 4-6

Ikú Iṣboṣeti

Nígbà tí ọmọ Saulu sì gbọ́ pé, Abneri kú ní Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Israẹli sì rẹ̀wẹ̀sì. Ọmọ Saulu sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Baanah, àti orúkọ èkejì ní Rekabu, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti ti àwọn ọmọ Benjamini (nítorí pé a sì ka Beeroti pẹ̀lú Benjamini). Àwọn ará Beeroti sì ti sálọ sí Gittaimu, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.

(Jonatani ọmọ Saulu sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìròyìn dé ní ti Saulu àti Jonatani láti Jesreeli wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sálọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sálọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mefiboṣeti.)

Àwọn ọmọ Rimoni, ará Beeroti, Rekabu àti Baanah sì lọ wọ́n sì wá síh ilé Iṣboṣeti ní ọ̀sán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́-kanrí. Sì wò ó, bí olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárín ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú alikama; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀ sì sálọ).

Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sálọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wọ́n sì gbé orí Iṣboṣeti tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọ̀tá rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kiri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba olúwa mi lónìí lára Saulu àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”

Dafidi sì dá Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú. 10 Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Saulu ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìhìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Siklagi, ẹni tí ó ṣe bí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìròyìn rere rẹ̀. 11 Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìkà ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láààyè.”

12 Dafidi sì fi àṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hebroni. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Iṣboṣeti, wọ́n sì sin ín ní ibojì Abneri ní Hebroni.

A fi Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli

(A)Gbogbo ẹ̀yà Israẹli sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa ń í ṣe. Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Saulu fi jẹ ọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Israẹli jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: Olúwa sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò ṣe olùṣọ́ Israẹli àwọn ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún Israẹli.’ ”

Gbogbo àgbàgbà Israẹli sì tọ ọba wá ní Hebroni, Dafidi ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hebroni, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba Israẹli.

(B)Dafidi sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba; ó sì jẹ ọba ní ogójì ọdún. Ó jẹ ọba ní Hebroni ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Juda: ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Israẹli àti Juda.

Dafidi fi agbára gba Jerusalẹmu

(C)Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn ará Jebusi, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dafidi pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dafidi kì yóò lè wá síhìn-ín.” Ṣùgbọ́n Dafidi fi agbára gba ìlú odi Sioni: èyí náà ni í ṣe ìlú Dafidi.

Dafidi sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jebusi, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dafidi kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.”

Dafidi sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ-ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dafidi. Dafidi mọ ògiri yí i ká láti Millo wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀. 10 Dafidi sì ń pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

11 (D)Hiramu ọba Tire sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, àti igi kedari, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dafidi. 12 Dafidi sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jẹ ọba lórí Israẹli, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀.

13 Dafidi sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jerusalẹmu wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hebroni bọ̀: wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dafidi. 14 (E)Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerusalẹmu; Ṣammua, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. 15 Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia. 16 Àti Eliṣama, àti Eliada, àti Elifeleti.

Dafidi ṣẹ́gun àwọn Filistini

17 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi. 18 Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní Àfonífojì Refaimu. 19 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?”

Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.”

20 Dafidi sì dé Baali-Perasimu, Dafidi sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọ̀tá mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baali-Perasimu. 21 Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.

22 (F)Àwọn Filistini sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní Àfonífojì Refaimu. 23 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òun sì wí pé, “Má ṣe gòkè lọ; ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Baka. 24 Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi Baka náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Filistini.” 25 Dafidi sì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un; ó sì kọlu àwọn Filistini láti Geba títí dé Geseri.

A gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu

(G)Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà. Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà. Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali.

Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.

Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Ussa kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pereṣi-Uṣa títí ó fi di òní yìí.

Dafidi sì bẹ̀rù Olúwa ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?” 10 Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. 11 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀.

12 (H)A sì rò fún Dafidi ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀. 13 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. 14 Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. 15 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.

16 Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

17 Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un: Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa. 18 Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 19 Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ Mikali

20 Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”

21 Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa. 22 Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”

23 Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.