Historical
Dafidi ṣe ètò ìkànìyàn
21 Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli. 2 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì wí fún Joabu àti àwọn olórí àwọn ènìyàn pé, “Lọ kí o ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti Beerṣeba títí dé Dani. Kí o sì padà mú iye wọn fún mi wa, kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.”
3 Ṣùgbọ́n Joabu dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa kí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọba olúwa mi, gbogbo wọn kì í ha ṣe ìránṣẹ́ olúwa ni? Kí ni ó dé tí olúwa mi ṣe fẹ́ ṣè yìí? Kí ni ó de tí yóò fi mú ẹ̀bi wá sórí Israẹli?”
4 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí tí Joabu. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu jáde lọ, ó sì la gbogbo Israẹli já, ó sí dé Jerusalẹmu. 5 Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún ọkùnrin tí ń kọ́ idà.
6 Ṣùgbọ́n Joabu kó àwọn Lefi àti Benjamini mọ́ iye wọn, nítorí àṣẹ ọba jẹ́ ìríra fún un. 7 Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Israẹli.
8 Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi.
9 Olúwa sì fi fún Gadi, aríran Dafidi pé. 10 “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Yan fún ara rẹ: 12 Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”
13 Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa nísinsin yìí, nítorí tí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi; Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.”
14 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn. 15 Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, Olúwa sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.
16 Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.
17 Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.”
18 Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. 19 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa.
20 Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́. 21 Bí Dafidi sì ti dé ọ̀dọ̀ Arauna, Arauna sì wò, ó sì rí Dafidi, ó sì ti ibi ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ jáde, ó sì wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi.
22 Dafidi sì wí fún Arauna pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ìwọ ó sì fi fún mi ni iye owó rẹ̀ pípé, kí a lè dá àjàkálẹ̀-ààrùn dúró lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.”
23 Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”
24 Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún Olúwa, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”
25 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà. 26 Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ọpẹ́. Ó sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi iná dá a lóhùn láti òkè ọ̀run wá lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ sísun.
27 Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí angẹli, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ rẹ̀. 28 Ní àkókò náà nígbà tí Dafidi sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Arauna ará Jebusi, ó sì rú ẹbọ sísun níbẹ̀. 29 Àgọ́ Olúwa tí Mose ti ṣe ní aginjù, àti pẹpẹ ẹbọ sísun wà lórí ibi gíga ní Gibeoni ní àkókò náà. 30 Ṣùgbọ́n Dafidi kò lè lọ síwájú rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ angẹli Olúwa.
22 Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.”
Ìmúrasílẹ̀ fún ilé tí a kọ́ fún ìsìn Ọlọ́run
2 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. 3 Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. 4 Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi.
5 Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.
6 Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 7 (A)Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi. 8 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńláńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi. 9 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀. 10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’
11 “Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. 12 Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́. 13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.
14 “Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé Olúwa ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn. 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
17 Nígbà náà Dafidi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli láti ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìṣẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn. 19 Nísinsin yìí, ẹ ṣí ọkàn yin páyà àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa.”
Àwọn ará Lefi
23 Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli.
2 Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. 3 Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlógún (38,000) 4 Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. 5 Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
6 Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Àwọn ọmọ Gerṣoni
7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni:
Laadani àti Ṣimei.
8 Àwọn ọmọ Laadani
Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joeli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
9 Àwọn ọmọ Ṣimei:
Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn.
Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.
10 Àti ọmọ Ṣimei:
Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.
11 Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.
Àwọn ará Kohati
12 Àwọn ọmọ Kohati:
Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.
13 (B)Àwọn ọmọ Amramu.
Aaroni àti Mose.
A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé. 14 Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.
15 Àwọn ọmọ Mose:
Gerṣomu àti Elieseri.
16 Àwọn ọmọ Gerṣomu:
Ṣubueli sì ni alákọ́kọ́.
17 Àwọn ọmọ Elieseri:
Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́.
Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.
18 Àwọn ọmọ Isari:
Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19 Àwọn ọmọ Hebroni:
Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì,
Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20 Àwọn ọmọ Usieli:
Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.
Àwọn ará Merari
21 Àwọn ọmọ Merari:
Mahili àti Muṣi.
Àwọn ọmọ Mahili:
Eleasari àti Kiṣi.
22 Eleasari sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.
23 Àwọn ọmọ Muṣi:
Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa 25 Nítorí pé Dafidi ti sọ pé Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé. 26 Àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀. 27 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa. 29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùwọ̀n. 30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. 31 Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.
32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.