Historical
Ìdájọ́ lórí àwọn àgbà Israẹli
11 Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn. 2 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú. 3 Wọ́n ní, ‘Kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’. 4 Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀.”
5 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, Ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín. 6 Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀.
7 “Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀. 8 Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. 9 Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10 Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. 11 Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀; Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. 12 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”
13 Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! OlúwaOlódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?”
14 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 15 “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’
Ìlérí pé Israẹli yóò padà
16 “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’
17 “Nítorí náà, wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’
18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò. 19 (A)Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. 20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 21 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”
22 Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn. 23 Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà. 24 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn.
Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, 25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.
Àpẹẹrẹ àwọn tó wà ní ìgbèkùn
12 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 (B)“Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.
3 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, ní ọ̀sán gangan ní ojú wọn, kúrò láti ibi tí ìwọ wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, wọn yóò sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 4 Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn ní ọ̀sán án gangan, nígbà tí ó bá sì di alẹ́, ní ojú wọn, máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe. 5 Dá ògiri lu ní ojú wọn, kí ìwọ sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde. 6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká ní ojú wọn, bo ojú rẹ, kí ìwọ má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ ní alẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe ààmì fún ilé Israẹli.”
7 Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kó ẹrù mi jáde ní ọ̀sán án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbe ẹrù mi lé èjìká nínú òkùnkùn ní ojú wọn.
8 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 9 “Ọmọ ènìyàn, Ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli tilẹ̀ bi ọ́ pé, ‘Kí ni ohun tí o ń ṣe túmọ̀ sí?’
10 “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ-aládé Jerusalẹmu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó wà ní àárín rẹ. 11 Sọ fún wọn pé, Èmi jẹ́ ààmì fún yín’.
“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn.
12 “Ọmọ-aládé tí ó wà ní àárín wọn yóò di ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀. 13 Èmi yóò ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, Èmi yóò sì mú lọ sí Babeli, ní ilẹ̀ Kaldea, ṣùgbọ́n kò ní fojúrí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí. 14 Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ni Èmi yóò túká sí afẹ́fẹ́, èmi yóò sì tún fi idà lé wọn kiri.
15 “Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà tí mo bá tú wọn ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri. 16 Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, ní ọwọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.”
17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà. 19 Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀. 20 Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
21 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 22 “Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’? 23 Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ. 24 Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ tí ó ń pọ́n ni mọ́ ní àárín ilé Israẹli. 25 Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ”
26 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 27 “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ìwọ rí, ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’
28 “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún síwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.