Read the Gospels in 40 Days
Sakeu agbowó òde
19 (A)Jesu sì wọ Jeriko lọ, ó sì ń kọjá láàrín rẹ̀. 2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀. 3 Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú. 4 Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.
5 Nígbà tí Jesu sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sakeu! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lónìí.” 6 Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.
7 (B)Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”
8 (C)Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”
9 (D)Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu. 10 Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
Òwe minas mẹ́wàá
11 (E)Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí. 12 (F)(G)Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. 13 Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’
14 “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’
15 “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.
16 “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’
17 (H)“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’
18 “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’
19 “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’
20 “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan; 21 Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22 “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn; 23 Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’
24 “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó minas mẹ́wàá.’
25 “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’
26 (I)“Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”
Ó wọ ilé pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
28 (J)Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 29 (K)Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30 Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”
32 (L)Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. 33 Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”
34 (M)Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”
35 Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á. 36 (N)Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.
37 Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí;
38 (O)Wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
39 (P)Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
40 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”
41 (Q)Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42 Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43 (R)Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 44 (S)Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”
Jesu nínú tẹmpili
45 (T)Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46 Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”
47 (U)Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Wọ́n béèrè nípa àṣẹ Jesu
20 (V)Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìhìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i. 2 (W)Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
3 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi. 4 Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”
5 Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ 6 (X)Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”
7 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
8 Jesu sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
Òwe àwọn ayálégbé
9 (Y)(Z) Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́. 10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 11 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 12 Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.
13 “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’
14 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’ 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.
“Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn? 16 (AA)Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”
17 (AB)Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?
18 (AC)Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”
19 (AD)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.
Sísan owó orí fún Kesari
20 (AE)Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́. 21 (AF)Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. 22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”
23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, 24 “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”
25 (AG)Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
Àjíǹde àti ìgbéyàwó
27 (AH)(AI) Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, 28 (AJ)wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. 29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. 31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. 32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. 33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”
34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. 35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. 36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. 37 (AK)Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”
39 (AL)Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” 40 (AM)Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.
Ọmọ ta ni Jesu n ṣe
41 (AN)Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? 42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:
“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
44 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
45 (AO)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, 46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; 47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.