Chronological
Kíkùn àwọn ènìyàn àti iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa
11 Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etí ìgbọ́ Olúwa. Ìbínú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárín wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó. 2 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mose, Mose sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú. 3 Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tabera nítorí pé, iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrín wọn.
Ẹran àparò láti ọ̀dọ̀ Olúwa
4 (A)Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí! 5 Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Ejibiti, apálà, bàrà, ewébẹ̀, àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn 6 Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi manna nìkan tí a rí yìí!”
7 Manna náà dàbí èso korianderi, ìrísí rẹ̀ sì dàbí oje igi. 8 Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe. 9 Nígbà tí ìrì bá ẹ̀ sí ibùdó lórí ni manna náà máa ń bọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
10 Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú. 11 Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí. 12 Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn. 13 Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sọkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’ 14 Èmi nìkan kò lè dágbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi. 15 Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojúrere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”
16 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi. 17 Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.
18 “Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́. 19 Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán, 20 Ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan: títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín: nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ”
21 Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’ 22 Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?”
23 Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí? Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ.”
24 Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká. 25 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkùùkuu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́.
26 Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin (70) àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́. 27 Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”
28 Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!”
29 Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!” 30 Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́.
31 Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú Òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká. 32 Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí: Ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó. 33 Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrín eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn. 34 (B)Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kibirotu-Hattaafa nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúwà oúnjẹ sí.
35 Àwọn ènìyàn yòókù sì gbéra láti Kibirotu-Hattaafa lọ pa ibùdó sí Haserotu wọ́n sì dúró níbẹ̀.
Miriamu Àti Aaroni tako Mose
12 Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia. 2 Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.
3 (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).
4 Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta. 5 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú, 6 Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi:
“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín
Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran,
Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.
7 (C)Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi:
ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi.
8 (D)Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,
ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,
ó rí àwòrán Olúwa
Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù
láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”
9 Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.
10 Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀, 11 Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn. 12 Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”
13 Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!”
14 (E)Olúwa sì dá Mose lóhùn, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.” 15 Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà.
16 Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Haserotu, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Parani.
Ṣíṣe Ayọ́lẹ̀wò sí ilẹ̀ Kenaani
13 Olúwa sọ fún Mose pé, 2 “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.”
3 Mose sì rán wọn jáde láti Aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.
4 Orúkọ wọn nìwọ̀nyí:
láti inú ẹ̀yà Reubeni Ṣammua ọmọ Sakkuri;
5 láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;
6 láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne;
7 Láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu;
8 Láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni;
9 Láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu;
10 Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi;
11 Láti inú ẹ̀yà Manase, (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;
12 Láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;
13 Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.
14 Láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;
15 Láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.
16 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)
17 Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè 18 Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19 Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi? 20 Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)
21 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati. 22 Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.) 23 Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24 Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀. 25 Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.
Ìròyìn nípa ilẹ̀ tí wọ́n yẹ̀ wò
26 Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí. 28 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀. 29 Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá Òkun àti ní etí bèbè Jordani.”
30 Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.”
31 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.” 32 Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀. 33 (F)A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.