Chronological
Ọgbọ́n
7 Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ
ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ
2 Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀
ju ibi àsè
nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn
kí alààyè ní èyí ní ọkàn.
3 Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ,
ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú,
ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.
4 Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
5 Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,
ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
6 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò
ni ẹ̀rín òmùgọ̀,
Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.
7 Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,
àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.
8 Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,
sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
9 Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ
nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.
10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”
Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára
ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbò
gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò
ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí
pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.
13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:
“Ta ni ó le è to
ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”
14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,
ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó
Ọlọ́run tí ó dá èkínní
náà ni ó dá èkejì
nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí
ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.
15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:
Ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀
ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.
16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ
tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ
kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè
Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
18 Ó dára láti mú ọ̀kan
kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀
Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.
19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára
ju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú.
20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé
tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.
21 Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ
pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnrarẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.
23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,
“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”
ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.
24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,
ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀
ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
25 Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀,
láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n
àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́
búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.
26 Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ
obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,
tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté
tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,
ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.
27 Oniwaasu wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:
“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.
28 Nígbà tí mo sì ń wá a kiri
ṣùgbọ́n tí n kò rí i
mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún
ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,
kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn.
29 Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí:
Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,
ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”
8 Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn?
Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?
Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán
ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.
Pa òfin ọba mọ́
2 Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. 3 Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. 4 Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,
àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.
6 Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe,
ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.
7 Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá,
ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀?
8 Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró
nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.
Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;
bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.
9 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀. 10 Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.
11 Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12 Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13 Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.
14 Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. 15 Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.
16 Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. 17 Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.
Àyànmọ́ kan náà fún gbogbo wọn
9 Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. 2 Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ.
Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere
bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀
bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra
bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.
3 Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. 4 Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!
5 Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú
ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan
wọn kò ní èrè kankan mọ́,
àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
6 Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn
àti ìlara wọn ti parẹ́:
láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín
nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.
7 Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe. 8 Máa wọ aṣọ funfun nígbàkúgbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. 9 Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.
11 Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn
Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára
tàbí ogun fún alágbára
bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n
tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye
tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;
ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
12 Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:
Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú
tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi
tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.
Ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ lọ
13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn: 14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16 Nítorí náà mo sọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.
17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ
ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
18 Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,
ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.
10 Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,
bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.
2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.
3 Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,
òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n
a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.
4 Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,
ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;
ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.
5 Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,
irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.
6 A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,
nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.
7 Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,
nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.
8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.
9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.
10 Bí àáké bá kú
tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;
yóò nílò agbára púpọ̀
ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.
11 Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,
kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.
12 Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́
ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.
13 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;
ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.
14 Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀.
Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀
ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?
15 Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágara
kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.
16 Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.
17 Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́
ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,
fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.
18 Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì
bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.
19 Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,
wáìnì a máa mú ayé dùn,
ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.
20 Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,
tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,
nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ
ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.
Àkàrà lórí omi
11 Fún àkàrà rẹ sórí omi,
nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà
2 Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,
nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀.
3 Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi,
ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí
Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá
níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.
4 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.
5 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́
tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run
ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.
6 Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́,
nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere
bóyá èyí tàbí ìyẹn
tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.
Rántí ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ
7 Ìmọ́lẹ̀ dùn;
Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.
8 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún
tí ó le è lò láyé
ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn
nítorí wọn ó pọ̀
Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.
9 Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe
kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.
Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ
àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí
ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni
Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.
10 Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ
kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò
nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.
12 Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ
ní ọjọ́ èwe rẹ,
nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé
àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,
“Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn”
2 Kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀
àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,
àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;
3 Nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì
tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,
nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,
tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;
4 Nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì
tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;
nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ
ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.
5 Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga
àti ti ìfarapa ní ìgboro;
nígbà tí igi almondi yóò tanná
àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ
tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́
nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé
tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.
6 Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,
tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;
kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,
tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.
7 Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,
tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.
8 “Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.
“Gbogbo rẹ̀ asán ni!”
Òpin gbogbo ọrọ̀
9 Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. 10 Oniwaasu wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.
11 Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí ìṣó tí a kàn pọ̀ dáradára, tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni. 12 Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ mi, gba ìmọ̀ràn.
Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.
13 Nísinsin yìí,
òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé:
Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,
nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.
14 Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́
àti ohun ìkọ̀kọ̀,
kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.