Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 18-20

Iṣẹ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi

18 Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín. Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Lefi láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ ẹ̀rí. (A)Àwọn ni ó yẹ láti dúró fún ọ àti láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ti Àgọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ tí a sì yà sí mímọ́ tàbí ibi pẹpẹ, tàbí gbogbo wọn àti ìwọ ló máa kú. Ó yẹ kí wọ́n darapọ̀ mọ́ ọ láti jẹ ìyà iṣẹ́ fún àìtọ́jú ibi ti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ tí ó wà ní ibi àgọ́, àti wí pé kò sí àlejò tí ó le wá sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí o wà.

“Kí o sì mójútó iṣẹ́ ibi mímọ́ àti iṣẹ́ ibi pẹpẹ, kí ìbínú má ba wá sí orí àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Lefi kún àwọn ọmọ Israẹli yòókù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún Olúwa láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé. Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni yóò mójútó iṣẹ́ àlùfáà yín fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ibi pẹpẹ àti ti ẹ̀yin aṣọ títa, ẹ ó sì máa ṣiṣẹ́ ibi pẹpẹ àti nínú aṣọ tí a ta. Mo fún ọ ní iṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ṣùgbọ́n àlejò tí ó bá súnmọ́ tòsí ibi ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run ni a ó pa.”

Ẹbọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdí gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe. Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpín wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 10 Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

11 “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́.

12 “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè. 13 Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ, Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́.

14 (B)“Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ní Israẹli jẹ́ tìrẹ. 15 Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́. 16 Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún (20) gera.

17 “Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́; wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí Olúwa. 18 Ẹran wọn gbọdọ̀ jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ. 19 Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n mú wá fún Olúwa ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú Olúwa fún ìwọ àti ọmọ rẹ.”

20 Olúwa sọ fún Aaroni pé, “O kò ní ní ogún nínú ilẹ̀ wọn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ní ní ìpín láàrín wọn, Èmi ni ìpín àti ogún rẹ láàrín àwọn ọmọ Israẹli.

21 “Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé 22 Láti ìsinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú 23 Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 24 Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn: Wọn kò nígba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.”

25 Olúwa sọ fún Mose pé, 26 “Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa. 27 A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa. 28 Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún Olúwa láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ Olúwa fún Aaroni àlùfáà. 29 Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín Olúwa èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’

30 “Sọ fún àwọn ọmọ pé: ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín. 31 Ìwọ àti àwọn ìdílé rẹ̀ le jẹ èyí tí ó kù ní ibikíbi gbogbo. Nítorí pé ó jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ rẹ níbi àgọ́ ìpàdé. 32 Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú.’ ”

Omi Ìwẹ̀nùmọ́

19 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín: Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́. Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ. Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé. Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀. Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun. Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

“Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn.

11 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 12 Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́. 13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.

14 “Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́: Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, 15 Gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.

16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.

17 “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí. 18 Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá. 19 Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́, Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́. 20 Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́. 21 Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn.

“Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 22 Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”

Omi láti inú àpáta

20 Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.

(C)Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni, Wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú Olúwa! Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí? Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!”

Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n. Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.”

Báyìí ni Mose mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un. 10 Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” 11 Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

12 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”

13 Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn.

Edomu ṣẹ́ Israẹli

14 Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé:

“Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Israẹli sọ: Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa. 15 Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa, 16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti.

“Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ. 17 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀-èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kànga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”

18 Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé:

“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”

19 Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé:

“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkan kan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

20 Wọ́n tún dáhùn wí pé:

“Ẹ kò lè kọjá.”

Nígbà náà ni Edomu jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ-ogun. 21 Nígbà tí Edomu sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Israẹli yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Ikú Aaroni

22 Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì jáde láti Kadeṣi wọ́n sì wá sí orí òkè Hori. 23 Ní orí òkè Hori, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Edomu Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 24 “Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba. 25 (D)Mú Aaroni àti ọmọ rẹ̀ Eleasari lọ sí orí òkè Hori. 26 Bọ́ aṣọ Aaroni kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, nítorí pé Aaroni yóò kú síbẹ̀.”

27 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ: Wọ́n lọ sí orí òkè Hori ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn. 28 Mose bọ́ aṣọ Aaroni ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, Aaroni sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mose àti Eleasari sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, 29 Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Aaroni ti kú, gbogbo ilé Israẹli ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.