Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Onidajọ 10-12

Tola

10 Lẹ́yìn ikú Abimeleki, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Isakari tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, dìde láti gba Israẹli sílẹ̀. Ní Ṣamiri tí ó wà ní òkè Efraimu ni ó gbé. Ó ṣe àkóso Israẹli ní ọdún mẹ́tàlélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Ṣamiri.

Jairi

Jairi ti ẹ̀yà Gileadi ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Israẹli ní ọdún méjìlélógún. Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó n gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gileadi, tí a pe orúkọ wọn ní Hafoti-Jairi títí di òní. Nígbà tí Jairi kú wọ́n sin ín sí Kamoni.

Jefta

Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa. Wọ́n sin Baali àti Aṣtoreti àti àwọn òrìṣà Aramu, òrìṣà Sidoni, òrìṣà Moabu, òrìṣà àwọn ará Ammoni àti òrìṣà àwọn ará Filistini. Nítorí àwọn ará Israẹli kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn ín mọ́, ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Filistini àti Ammoni láti jẹ ẹ́ ní ìyà. Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjì-dínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní ìlà-oòrùn odò Jordani ní ilẹ̀ àwọn ará Amori lára (èyí nì ní Gileadi). Àwọn ará Ammoni sì la odò Jordani kọjá láti bá Juda, Benjamini àti àwọn ará ilé Efraimu jagun: Israẹli sì dojúkọ ìpọ́njú tó lágbára. 10 Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli ké pe Olúwa wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Baali.”

11 Olúwa sì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Ejibiti, Amori, Ammoni, Filistini, 12 àwọn ará Sidoni, Amaleki pẹ̀lú Maoni ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn? 13 Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́. 14 Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín. Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín!”

15 Àwọn ọmọ Israẹli sì dá Olúwa lóhùn pé, “Àwa ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ nání àsìkò yìí.” 16 Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàrín wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Israẹli mọ́.

17 Nígbà tí àwọn ará Ammoni kógun jọ ní Gileadi láti bá Israẹli jà, àwọn ọmọ Israẹli gbárajọpọ̀, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mispa. 18 Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gileadi wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ ṣígun si àwọn ará Ammoni ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gileadi.”

11 Jefta ará Gileadi jẹ́ akọni jagunjagun. Gileadi ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ panṣágà. Ìyàwó Gileadi sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jefta jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ (ọmọ panṣágà) ọmọ obìnrin mìíràn.” Jefta sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tobu, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ òfin lójú parapọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri.

Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ammoni dìde ogun sí àwọn Israẹli, Ó sì ṣe nígbà tí àwọn Ammoni bá Israẹli jagun, àwọn àgbàgbà Gileadi tọ Jefta lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tobu. Wọ́n wí fún Jefta wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ammoni.”

Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kórìíra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?”

Àwọn àgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ammoni, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gileadi.”

Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ammoni jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́?”

10 Àwọn àgbàgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.” 11 Jefta sì tẹ̀lé àwọn àgbàgbà Gileadi lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jefta sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mispa.

12 Jefta sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ammoni pé, “Kí ni ẹ̀sùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?”

13 Ọba àwọn Ammoni dá àwọn oníṣẹ́ Jefta lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli jáde ti Ejibiti wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Arnoni dé Jabbok, àní dé Jordani, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”

14 Jefta sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ammoni 15 ó sì wí fún un pé:

“Báyìí ni Jefta wí: àwọn ọmọ Israẹli kò gba ilẹ̀ Moabu tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ammoni. 16 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ejibiti àwọn ọmọ Israẹli la aginjù kọjá lọ sí ọ̀nà Òkun pupa wọ́n sì lọ sí Kadeṣi. 17 Nígbà náà Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Edomu pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Edomu kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Moabu bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Israẹli dúró sí Kadeṣi.

18 “Wọ́n rin aginjù kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Edomu àti ti Moabu sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà-oòrùn Moabu, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Arnoni. Wọn kò wọ ilẹ̀ Moabu, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Arnoni wà.

19 “Nígbà náà ni Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Heṣboni, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí ibùgbé wa.’ 20 Ṣùgbọ́n Sihoni kò gba Israẹli gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jahisa láti bá Israẹli jagun.

21 Olúwa Ọlọ́run Israẹli sì fi Sihoni àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Israẹli sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé ní agbègbè náà, 22 wọ́n gbà gbogbo agbègbè àwọn ará Amori, láti Arnoni tí ó fi dé Jabbok, àti láti aginjù dé Jordani.

23 “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti lé àwọn ará Amori kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Israẹli, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà? 24 Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kemoṣi òrìṣà rẹ fi fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa. 25 Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Israẹli bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí? 26 Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà? 27 Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàrín àwọn ọmọ Israẹli àti àwọn ará Ammoni.”

28 Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ammoni kò fetí sí iṣẹ́ tí Jefta rán sí i.

29 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jefta òun sì la Gileadi àti Manase kọjá. Ó la Mispa àti Gileadi kọjá láti ibẹ̀, ó tẹ̀síwájú láti bá àwọn ará Ammoni jà. 30 Jefta sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ammoni lé mi lọ́wọ́, 31 Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ó bá jáde láti ẹnu-ọ̀nà ilé mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ammoni ní àlàáfíà, yóò jẹ́ ti Olúwa, èmi yóò sì fi rú ẹbọ bí ọrẹ ẹbọ sísun.”

32 Jefta sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ammoni jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́. 33 Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní à pa tán láti Aroeri títí dé agbègbè Minniti, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Keramimu. Báyìí ni Israẹli ti ṣẹ́gun àwọn ará Ammoni.

34 Nígbà tí Jefta padà sí ilé rẹ̀ ní Mispa, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú timbrili àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan. 35 Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí Olúwa ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le sẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.”

36 Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí Olúwa ti gba ẹ̀san fún ọ lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ará Ammoni. 37 Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láààyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n sọkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúńdíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.”

38 Jefta dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láààyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yòókù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n sọkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó. 39 Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúńdíá tí kò mọ ọkùnrin rí.

Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Israẹli 40 wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrín ọdún àwọn obìnrin Israẹli a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jefta ti Gileadi.

Jefta àti Efraimu

12 Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”

Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn. Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, Èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”

Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.” Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣíbólétì.’ ” Tí ó bá ní, “Síbólé tì,” torí pé kò ní mọ̀ọ́ pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléní-ogójì ọkùnrin.

Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi.

Ibsani, Eloni àti Abdoni

Lẹ́yìn Jefta, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ibsani ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje. 10 Lẹ́yìn náà ni Ibsani kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹtilẹhẹmu.

11 Lẹ́yìn rẹ̀, Eloni ti ẹ̀yà Sebuluni ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́wàá. 12 Eloni sì kú, wọ́n sì sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.

13 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hileli tí Piratoni n ṣe àkóso Israẹli. 14 Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin (70) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́jọ. 15 Abdoni ọmọ Hileli sì kú, wọ́n sin ín sí Piratoni ní ilé Efraimu ní ìlú òkè àwọn ará Amaleki.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.