Chronological
Juda àti Tamari
38 Ní àkókò náà, Juda lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Adullamu kan tí ń jẹ́ Hira. 2 Juda sì pàdé ọmọbìnrin Kenaani kan níbẹ̀ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua. Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lòpọ̀; 3 ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Eri. 4 Ó sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Onani. 5 Ó sì tún bí ọmọkùnrin mìíràn, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣela. Ní Kesibu ni ó wà nígbà tí ó bí i.
6 Juda sì fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Tamari. 7 Ṣùgbọ́n Eri àkọ́bí Juda ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á.
8 Nígbà náà ni Juda wí fún Onani, “Bá aya arákùnrin rẹ lòpọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin rẹ.” 9 Ṣùgbọ́n Onani mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀. 10 Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú.
11 Nígbà náà ni Juda wí fún Tamari, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣela yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù.” Nígbà náà ni Tamari ń lọ gbé ilé baba rẹ̀.
12 Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ.
13 Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.” 14 Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
15 Nígbà tí Juda rí i, ó rò pé panṣágà ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀. 16 Láìmọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà, ó wí pé, “Wá kí èmi kí ó lè wọlé tọ̀ ọ́.”
Òun sì wí pé “Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè wọlé tọ̀ mí.”
17 Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ sí ọ láti inú agbo ẹran.”
Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?”
18 Juda sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?”
Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípasẹ̀ rẹ̀. 19 Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà.
20 Juda sì rán ọmọ ewúrẹ́ náà láti ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adullamu náà lọ láti gba ògo nnì wá lọ́wọ́ obìnrin náà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀. 21 Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni alágbèrè ojúbọ òrìṣà tí ó wà ní etí ọ̀nà Enaimu wà?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbí.”
22 Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Juda ó wí fún un pé, “Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbẹ̀.”
23 Nígbà náà ni Juda wí pé, “Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà. Mo sá à fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun.”
24 Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.”
Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”
25 Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.”
26 Juda sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣela ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà.
27 Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó. Ìbejì ọkùnrin ni ó bí. 28 Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.” 29 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Tamari sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Peresi. 30 Nígbà náà ni èkejì tí a ti so okùn olódòdó mọ́ lọ́rùn ọwọ́ jáde, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ni Sera.
Josẹfu àti aya Potiferi
39 (A)Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potiferi, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀.
2 Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. 3 Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. 4 Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. 5 Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko. 6 Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀.
Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, 7 lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”
8 Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. 9 Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” 10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.
11 Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. 12 Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.
13 Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, 14 ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. 15 Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”
16 Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. 17 Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. 18 Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”
19 Nígbà tí Potiferi gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. 20 Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.
Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, 21 (B)Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà). 22 Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. 23 Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.
Agbọ́tí àti alásè
40 Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn. 2 Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè, 3 Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà. 4 Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn.
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀. 5 Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
6 Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn. 7 Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”
8 Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.”
Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”
9 Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, 10 Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n. 11 Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”
12 Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá. 14 Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín. 15 Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”
16 Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá: Mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí, 17 Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.”
18 Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta. 19 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”
20 Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n. 21 Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́, 22 Ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.
23 Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Josẹfu mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.