Chronological
Jakọbu gbáradì láti pàdé Esau
32 Jakọbu sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn angẹli Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀. 2 Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run ni èyí!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Mahanaimu.
3 Jakọbu sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Esau arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Seiri ní orílẹ̀-èdè Edomu. 4 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí 5 Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”
6 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irínwó (400) ọkùnrin.”
7 Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jakọbu fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ìbákasẹ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 8 Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Esau bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”
9 Nígbà náà ni Jakọbu gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Abrahamu baba mi, àti Ọlọ́run Isaaki baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’ 10 Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì. 11 Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Esau arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. 12 (A)Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn Òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ”
13 Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. 14 Igba ewúrẹ́ (200), ogún (20) òbúkọ, igba (200) àgùntàn, ogún (20) àgbò, 15 Ọgbọ̀n (30) abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì (40) abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá (10), ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá (10). 16 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.”
17 Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Esau bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ, 18 Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”
19 Jakọbu sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Esau nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20 Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. 21 Nítorí náà ẹ̀bùn Jakọbu ṣáájú rẹ̀ lọ, Jakọbu pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́.
Jakọbu bá Ọlọ́run ja ìjàkadì
22 Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. 23 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. 24 (B)Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. 26 Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”
Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”
27 Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.
Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”
28 (C)Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”
29 (D)Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”
Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.
30 Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”
31 Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀. 32 Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kì í fi í jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jakọbu ti bẹ̀rẹ̀.
Jakọbu àti Esau pàdé
33 Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irínwó ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. 2 Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá. 3 Jakọbu fúnrarẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ Esau, arákùnrin rẹ̀.
4 Ṣùgbọ́n Esau sáré pàdé Jakọbu, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnukò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sọkún. 5 Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?”
Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”
6 Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba. 7 Lẹ́yìn náà ni Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Josẹfu àti Rakeli dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú.
8 Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?”
Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.”
9 Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”
10 Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi. 11 Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á.
12 Nígbà náà ni Esau wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.”
13 Ṣùgbọ́n Jakọbu wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèkéé. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn ṣe mọ lọ, wọ́n lè kú. 14 Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ síwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Seiri.”
15 Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.”
Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?”
16 Ní ọjọ́ náà gan an ni Esau padà lọ sí Seiri. 17 Jakọbu sì lọ sí Sukkoti, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Sukkoti.
18 Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu tí Padani-Aramu dé: Àlàáfíà ni Jakọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà. 19 (E)Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori tí í ṣe baba Ṣekemu. 20 Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Israẹli (Ọlọ́run Israẹli).
Dina àti àwọn ará Ṣekemu
34 Ní ọjọ́ kan, Dina ọmọbìnrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò. 2 Nígbà tí Ṣekemu ọmọ ọba Hamori ará Hifi rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀ 3 Ọkàn rẹ sì fà sí Dina ọmọ Jakọbu gan an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀ ìfẹ́. 4 Ṣekemu sì wí fún Hamori baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”
5 Nígbà tí Jakọbu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dina ọmọbìnrin òun ní ògo jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.
6 Hamori baba Ṣekemu sì jáde wá láti bá Jakọbu sọ̀rọ̀. 7 Àwọn ọmọ Jakọbu sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí tí ó ṣe ohun búburú ní Israẹli, ní ti ó bá ọmọbìnrin ọmọ Jakọbu lòpọ̀—irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.
8 Hamori sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣekemu fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya. 9 Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrín ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa. 10 Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”
11 Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà. 12 Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”
13 Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́. 14 Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa. 15 Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà. 16 Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrín yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín. 17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”
18 Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. 19 Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé baba rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jakọbu. 20 Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀. 21 Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú. 22 Ṣùgbọ́n kín ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn 23 Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.”
24 Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà.
25 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà. 26 Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde. 27 Àwọn ọmọ Jakọbu sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́. 28 Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko. 29 Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátápátá ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.
30 Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.”
31 Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.