Chronological
Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀
40 Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé:
2 “Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?
Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”
3 Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,
4 “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?
Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
5 Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;
lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”
6 Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé:
7 “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,
èmi ó bi ọ léèrè,
kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
8 “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?
Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo
9 Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run
tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
10 Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,
tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
11 Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;
kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀
kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13 Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,
kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú
14 Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,
ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,
tí mo dá pẹ̀lú rẹ,
òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16 Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17 Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari;
Iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ;
Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;
síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20 Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,
níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,
lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
22 Igi lótusì ṣíji wọn bò o;
igi arọrọ odò yí i káàkiri.
23 Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;
ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
24 Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,
tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú láti pe Jobu níjà
41 “Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde?
Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
2 Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú,
tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
3 Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀
rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
4 Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí?
Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
5 Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni,
tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
6 Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí?
Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
7 Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀,
tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
8 Fi ọwọ́ rẹ lé e lára,
ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
9 Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán;
ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
10 Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè;
Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
11 Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un?
Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
12 “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani,
tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
13 Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀?
Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?
14 Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀?
Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
15 Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀;
ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí ààmì èdìdì.
16 Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀
tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
17 Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀;
wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.
18 Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́,
ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.
19 Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá,
ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.
20 Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá,
bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.
21 Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná,
ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
22 Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí,
àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀,
wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.
24 Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta,
àní, ó le bi ìyá ọlọ.
25 Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù;
nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
26 Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà,
ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.
27 Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ
àti idẹ si bi igi híhù.
28 Ọfà kò lè mú un sá;
òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.
29 Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko;
ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.
30 Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀,
ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.
31 Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò;
ó sọ̀ agbami Òkun dàbí kólòbó ìkunra.
32 Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀;
ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.
33 Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,
tí a dá láìní ìbẹ̀rù.
34 Ó bojú wo ohun gíga gbogbo,
ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”
Ìrònúpìwàdà Jobu
42 Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé:
2 “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,
àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
3 Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?
Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,
ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.
4 “Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí,
èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,
ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’
5 Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,
ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.
6 Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,
mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”
Ọlọ́run bùkún Jobu
7 Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ. 8 Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe. 9 Bẹ́ẹ̀ ní Elifasi, ara Temani, àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Olúwa sì gbọ́ àdúrà Jobu.
10 Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí 11 Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.
12 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá-méje àgùntàn, ẹgbàá-mẹ́ta ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 13 Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 14 Ó sì sọ orúkọ àkọ́bí ní Jemima, àti orúkọ èkejì ni Kesia àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kereni-Happuki. 15 Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.
16 Lẹ́yìn èyí Jobu wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin. 17 Bẹ́ẹ̀ ni Jobu kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.