Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 21-23

Jobu dá Sofari lóhùn

21 Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé:

“Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi,
    kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.
Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà
    ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.

“Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí?
    Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?
Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,
    kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.
Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,
    ìwárìrì sì mú mi lára.
Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní
    ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú
    wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.
Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀
    ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
10 Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì
    tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;
11 Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn
    wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
12 Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti
    haapu, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
13 Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn
    sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.
14 Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’
    Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
15 Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in?
    Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?
16 Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa
    ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.

17 “Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú?
    Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn,
    tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?
18 Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́,
    àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.
19 Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’
    Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.
20 Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀,
    yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.
21 Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,
    nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?

22 “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀?
    Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.
23 Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀,
    ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.
24 Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú,
    egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.
25 Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀,
    tí kò sì fi inú dídùn jẹun.
26 Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀,
    kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.

27 “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti
    àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.
28 Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé,
    àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’
29 Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà?
    Ẹ̀yin kò mọ̀ ààmì wọn, pé
30 ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun.
    A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.
31 Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú,
    ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
32 Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú,
    a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.
33 Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.
    Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́
    lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.

34 “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán,
    bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”

Èsì Elifasi

22 Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:

(A)“Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?
    Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?
Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ?
    Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù
    Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?
Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi,
    àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?
Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí,
    ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.
Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu,
    ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.
Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀,
    ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.
Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo;
    Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.
10 Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri,
    àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,
11 Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran;
    Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12 “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?
    Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!
13 Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?
    Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?
14 Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un,
    tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.
15 Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn
    ènìyàn búburú tí rìn?
16 A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn;
    ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn;
17 Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!
    Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’
18 Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn!
    Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!
19 Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀,
    àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,
20 ‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò,
    iná yóò sì jó oró wọn run.’

21 “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
    nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
22 Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
    kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.
23 Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró:
    Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
24 Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀
    lórí erùpẹ̀ àti wúrà ofiri lábẹ́ òkúta odò,
25 Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,
    àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
26 Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,
    ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
27 Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,
    ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;
    ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.
29 Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,
    nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’
    Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!
30 Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,
    a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Èsì Jobu

23 Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé:

“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;
    ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá
    Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,
    ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá
    mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?
    Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,
    níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.

“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú,
    òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:
Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i,
    ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10 Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,
    nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11 Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀;
    ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.
12 Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀,
    èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.

13 “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?
    Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14 Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;
    nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16 Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,
    Olódùmarè sì ń dààmú mi.
17 Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,
    bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.