Chronological
Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Ejibiti
46 (A)Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn orílẹ̀-èdè:
2 Ní ti Ejibiti:
Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
3 “Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,
kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!
4 Ẹ di ẹṣin ní gàárì,
kí ẹ sì gùn ún.
Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ
pẹ̀lú àṣíborí yín!
Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,
kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
5 (B)Kí ni nǹkan tí mo tún rí?
Wọ́n bẹ̀rù,
wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,
wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.
Wọ́n sá,
wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,
ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”
ni Olúwa wí.
6 “Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,
tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.
Ní àríwá ní ibi odò Eufurate
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
7 “Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,
tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?
8 Ejibiti dìde bí odò náà,
bí omi odò tí ń ru.
Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’
Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
9 Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,
ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.
Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,
àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;
àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,
títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.
Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ
ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.
11 “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,
ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.
Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,
kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,
igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.
Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,
àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”
13 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:
14 “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,
sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:
‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,
nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’
15 Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?
Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
16 Wọn yóò máa ṣubú léraléra
wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.
Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà
sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,
kúrò níbi idà àwọn aninilára.’
17 Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,
‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,
ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’
18 “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba,
ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti
gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.
19 Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti
pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ
nítorí Memfisi yóò di ahoro
a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.
20 “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti
ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé,
ó dé láti àríwá.
21 Àwọn jagunjagun rẹ̀
dàbí àbọ́pa akọ màlúù.
Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,
wọn ó sì jùmọ̀ sá,
wọn kò ní le dúró,
Nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn
àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà.
22 Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá
bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.
Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,
gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.
23 Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”
ni Olúwa wí,
“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,
nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.
24 A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti,
a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”
25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26 Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.
27 “Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
má fòyà, ìwọ Israẹli.
Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,
àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.
Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,
kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.
28 Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.
Èmi kò ní run yín tán.
Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,
èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”
Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí àwọn ará Filistini
47 (C)Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa:
2 Báyìí ni Olúwa wí:
“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,
wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.
Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,
ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.
Àwọn ènìyàn yóò kígbe;
gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu
3 Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára
nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá
àti iye kẹ̀kẹ́ wọn.
Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;
ọwọ́ wọn yóò kákò.
4 Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé
láti pa àwọn Filistini run,
kí a sì mú àwọn tí ó là
tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò.
Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run,
àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.
5 Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.
A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́;
ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,
ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
6 “Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,
yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?
Padà sínú àkọ̀ rẹ;
sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’
7 Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,
nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,
nígbà tí ó ti pa á láṣẹ
láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”
Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Moabu
48 (D)Ní ti Moabu:
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí:
“Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun.
A dójútì Kiriataimu, a sì mú un,
ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.
2 Moabu kò ní ní ìyìn mọ́,
ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,
‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’
Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,
a ó fi idà lé e yín.
3 Gbọ́ igbe ní Horonaimu,
igbe ìrora àti ìparun ńlá.
4 Moabu yóò di wíwó palẹ̀;
àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.
5 Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti,
wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;
ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu
igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.
6 Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín;
kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.
7 Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,
a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,
Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn
pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.
8 Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,
ìlú kan kò sì ní le là.
Àfonífojì yóò di ahoro
àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,
nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
9 Fi iyọ̀ sí Moabu,
nítorí yóò ṣègbé,
àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro
láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.
10 “Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa,
ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
11 “Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá
bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,
tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì
kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.
Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,
òórùn rẹ̀ kò yí padà.
12 Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,”
ni Olúwa wí,
“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò
tí wọ́n ó sì dà á síta;
Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,
wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.
13 Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi,
bí ojú ti í ti ilé Israẹli
nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.
14 “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘ajagun ni wá,
alágbára ní ogun jíjà’?
15 A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;
a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”
ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
16 “Ìṣubú Moabu súnmọ́;
ìpọ́njú yóò dé kánkán.
17 Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.
Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ
títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’
18 “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,
kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,
ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni,
nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run
yóò dojúkọ ọ́
yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,
ìwọ tí ń gbé ní Aroeri.
Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà
‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’
20 Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀.
Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe!
Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé,
a pa Moabu run.
21 Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ
sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati,
22 sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu
23 sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni,
24 sórí Kerioti àti Bosra,
sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn.
25 A gé ìwo Moabu kúrò,
apá rẹ̀ dá,”
ni Olúwa wí.
26 “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí
nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,
jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀,
kí ó di ẹni ẹ̀gàn.
27 Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ?
Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè
tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́
nígbàkúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
28 Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta,
ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu.
Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀
sí ẹnu ihò.
29 “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu:
àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀
àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.
30 Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,”
ni Olúwa wí,
“ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan.
31 Nítorí náà, mo pohùnréré
ẹkún lórí Moabu fún àwọn
ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara
Mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
32 Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún
ìwọ àjàrà Sibma.
Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun,
wọn dé Òkun Jaseri.
Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ,
ìkórè èso àjàrà rẹ.
33 Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò
nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu.
Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí;
kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà,
wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.
34 “Ohùn igbe wọn gòkè
láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi,
láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi,
nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ
35 Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin sí
ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga
àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
36 “Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè,
ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.
37 Gbogbo orí ni yóò pá,
gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò,
gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́,
àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.
38 Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu,
àti ní ìta rẹ̀,
nítorí èmi ti fọ́ Moabu
bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,”
ni Olúwa wí.
39 “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú,
tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún!
Báwo ni Moabu ṣe yí
ẹ̀yìn padà ní ìtìjú!
Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti
ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”
40 Báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀
ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu.
41 Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu
yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.
42 A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí
orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa.
43 Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè
ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,”
ní Olúwa wí.
44 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún
ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn
ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta
nínú ọ̀fìn ní à ó mú
nínú okùn dídè nítorí tí
èmi yóò mú wá sórí
Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,”
ní Olúwa wí.
45 “Ní abẹ́ òjìji Heṣboni
àwọn tí ó sá dúró láìní agbára,
nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni,
àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni,
yóò sì jó iwájú orí Moabu run,
àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.
46 Ègbé ní fún ọ Moabu!
Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Kemoṣi ṣègbé
a kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì
àti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn.
47 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ
Moabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,”
ni Olúwa wí.
Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.