Chronological
24 Nígbà ìjọba Jehoiakimu, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun sí ilẹ̀ náà, Jehoiakimu sì di ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadnessari. 2 Olúwa sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì. 3 Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. 4 Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjì.
5 Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda? 6 Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
7 Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.
Jehoiakini ọba Juda
8 (A)Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjì-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu. 9 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.
10 Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, 11 Nebukadnessari ọba Babeli fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. 12 Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.
Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n. 13 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa. 14 Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárùn-ún ún, àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.
15 Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà. 16 Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli 17 Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.
Sedekiah ọba Juda
18 (B)Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó sì wá láti Libina. 19 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 20 Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.
Ìṣubú Jerusalẹmu
Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.
25 Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ìjọba Sedekiah. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli yan lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn iṣẹ́ ìdọ̀tí fi yí gbogbo rẹ̀ ká. 2 Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìgbóguntì títí di ọdún kọkànlá ti ọba Sedekiah.
3 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 4 Nígbà náà odi ìlú náà sì fọ́nká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun sálọ ní òru láti ẹnu-ọ̀nà bodè láàrín ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, àwọn ará Babeli wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sálọ sí ìkọjá Arabah. 5 Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, 6 wọ́n sì mú un.
Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 7 Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.
8 Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún ìkọkàn-dínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu; 9 ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńláńlá ni ó dáná sun. 10 Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 11 Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 12 Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko.
13 Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, Wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli. 14 Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, àti ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, èyí tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.
16 Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan, àti ìjókòó wọ̀n-ọn-nì tí Solomoni ti ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èló wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ. 17 Gíga ọ̀wọ́n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún, àti ọnà-orí rẹ̀ idẹ ni: àti gíga ọnà-orí náà ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti iṣẹ́ híhun náà, àti àwọn pomegiranate tí ó wà lórí ọnà-orí náà yíká, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́n yìí sì ni ọ̀wọ́n kejì pẹ̀lú iṣẹ́ híhun.
18 Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 19 Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú. 20 Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 21 Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
22 Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda. 23 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn. 24 Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.”
25 Ní oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá, ó sì kọlù Gedaliah àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ará Juda àti àwọn ará Babeli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mispa. 26 Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sálọ si Ejibiti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Babeli.
Wọ́n tú Jehoiakini sílẹ̀
27 (C)Ní ọdún kẹtà-dínlógójì ìgbèkùn Jehoiakini ọba Juda, ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹtà-dínlógbọ̀n oṣù, Efili-Merodaki ọba Babeli, ní ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ kúrò nínú túbú. 28 Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. 29 Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 30 Ní ojoojúmọ́, ọba fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè.
36 1 (A)Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah wọn sì fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu ni ipò baba rẹ̀.
Jehoahasi Ọba Juda
2 Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. 3 Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́ọ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà (100) àti tálẹ́ǹtì wúrà kan. 4 Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.
Jehoiakimu ọba Juda
5 (B)Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 6 Nebukadnessari ọba Babeli sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú un lọ sí Babeli. 7 Nebukadnessari kó nínú ohun èlò ilé Olúwa lọ si Babeli pẹ̀lú, ó sì fi wọn sí ààfin rẹ̀ ní Babeli.
8 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Jehoiakini ọba Juda
9 (C)Jehoiakini sì jẹ́ ẹni ọdún méjì-dínlógún (18) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa. 10 Ní àkókò òjò, ọba Nebukadnessari ránṣẹ́ sí i ó sì mú un wá sí Babeli, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé Olúwa, ó sì mú arákùnrin Jehoiakini, Sedekiah, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu.
Sedekiah ọba Juda
11 Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. 12 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa. 13 Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 14 Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu.
Ìṣubú Jerusalẹmu
15 Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe. 17 Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Babeli tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdébìnrin, wúńdíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadnessari lọ́wọ́. 18 Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Babeli, ńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀. 19 Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́.
20 Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára. 21 Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremiah.
22 (D)Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.
23 “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé:
“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jerusalẹmu ti Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.