Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ọbadiah

Ìran ti Ọbadiah.

(A)Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.

Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá:
    A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,
“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;
    ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,
    ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,
    tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,
ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,
    ‘ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,
    bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,
    láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”
    ni Olúwa wí.
“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,
    bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,
Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:
    wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?
Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,
    wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,
    tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ
    ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;
    àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,
    ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,
    Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,
    àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Temani,
    gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau
    ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.
10 Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,
    ìtìjú yóò bò ọ,
    a ó sì pa ọ run títí láé.
11 Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,
    ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,
tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ
    tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,
    ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.
12 Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,
    ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀
ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,
    ní ọjọ́ ìparun wọn
ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀
    ní ọjọ́ wàhálà wọn.
13 Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,
    ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀
    nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,
    ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.
14 Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà
    láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.
Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú
    wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

15 “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé
    lórí gbogbo àwọn kèfèrí.
Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;
    ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi
    bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí
Wọn yóò mu wọn yóò sì mu àmutẹ́rùn
    wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí
17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni
    Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́
àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn
18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná
    àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná
ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko
    wọn yóò fi iná sí i,
wọn yóò jo run.
    Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”
Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,
    àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni
ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.
    Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;
    Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani
    yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;
àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi
    yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní
21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá
    láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.
    Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.

Saamu 82-83

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Orin. Saamu ti Asafu.

83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
    Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
    bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
    wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
    kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;
    wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,
    ti Moabu àti ti Hagari
Gebali, Ammoni àti Amaleki,
    Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn
    láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani
    bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
10 Ẹni tí ó ṣègbé ní Endori
    tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,
    àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
12 Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní
    àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
    bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
    àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
    dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
    kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
    kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
    pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.