Chronological
Ìdáhùn Jobu
17 “Ẹ̀mí mi bàjẹ́,
ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú,
isà òkú dúró dè mí.
2 Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi,
ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
3 “Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́;
ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
4 Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye;
nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
5 Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè,
òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
6 “Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn;
níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
7 Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,
gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
8 Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,
ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9 Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,
àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
10 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín,
ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí;
èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
11 Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá,
àní ìrò ọkàn mi.
12 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán;
wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi;
mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.
14 Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi,
àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
15 ìrètí mi ha dà nísinsin yìí?
Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
16 Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,
nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”
Ìdáhùn Bilidadi
18 Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì;
ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ.
3 Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko,
tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?
4 Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀;
kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi?
Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?
5 “Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò,
Ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.
6 Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀,
fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.
7 Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ;
ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.
8 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n,
ó sì rìn lórí okùn dídẹ.
9 Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,
àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.
10 A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀,
a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà.
11 Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo,
yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.
12 Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi,
ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.
13 Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀;
ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.
14 A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,
a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.
15 Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀;
sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.
16 Gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀,
a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.
17 Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé,
kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.
18 A ó sì lé e láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn,
a ó sì lé e kúrò ní ayé.
19 Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,
Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.
20 Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀-oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà-oòrùn.
21 Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọn
ènìyàn búburú Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”
Ìdáhùn Jobu fún Bilidadi
19 Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí,
tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
3 Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí;
ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
4 Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́,
ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
5 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,
tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
6 Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,
ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7 “Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;
mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
8 Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,
Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
9 Ó ti bọ́ ògo mi,
ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10 Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,
ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11 Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi,
ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi,
wọ́n sì mọ odi yí mi ká,
wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
13 “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré,
àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
14 Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn,
àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
15 Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;
èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;
mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
17 Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi
ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
18 Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín:
Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,
àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi,
mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
21 “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,
ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
22 Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí
Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
23 “Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi
nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!
24 Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ
wọ́n sínú àpáta fún láéláé.
25 Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè
àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;
26 Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara
mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
27 Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi,
tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn;
ọkàn mi sì dákú ní inú mi.
28 “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!
Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’
29 Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù;
nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà,
Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”
Ìdáhùn Sofari
20 Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn,
àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.
3 Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye
mi sì dá mi lóhùn.
4 “Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,
5 pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni,
àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
6 Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run,
ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;
7 Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀;
àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
8 Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,
àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
9 Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà,
ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
11 Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀,
tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.
12 “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
13 bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
14 Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà,
ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde;
Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
16 Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú;
ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
17 Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì,
ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
18 Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì;
gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
19 Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n;
Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
20 “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀,
kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
21 Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀;
Nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
22 Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;
àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
23 Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun,
Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́,
yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
24 Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn;
ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
25 O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára;
idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá.
Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
26 òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀.
Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run
yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
27 Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn,
ayé yóò sì dìde dúró sí i.
28 Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun
ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
29 Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,
àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.