Beginning
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
Saamu 1–41
1 (A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
2 (B)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
sí Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò
lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
7 (C)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:
Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí, èmi ti di baba rẹ.
8 (D)Béèrè lọ́wọ́ mi,
Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.
4 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
ìwọ Ọlọ́run òdodo mi,
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4 (E)Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;
Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5 Ẹ rú ẹbọ òdodo
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
Olúwa, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o
mú mi gbé láìléwu.
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.
5 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
kíyèsi àròyé mi.
2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
ọba mi àti Ọlọ́run mi,
nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
5 Àwọn agbéraga kò le è dúró
níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
ni Olúwa yóò kórìíra.
7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi,
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
9 (F)Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;
ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
6 Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ
2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3 Ọkàn mi wà nínú ìrora.
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4 Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
6 Agara ìkérora mi dá mi tán.
Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 (G)Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.
7 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
5 Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.
6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
Jọba lórí wọn láti òkè wá;
8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
9 (H)Ọlọ́run Olódodo,
Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
8 Olúwa, Olúwa wa,
orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
ju àwọn ọ̀run lọ.
2 (I)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
àti ẹranko igbó,
8 ẹyẹ ojú ọrun,
àti ẹja inú Òkun,
àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
9 Olúwa, Olúwa wa,
Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.