Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
2 Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
3 Ẹ fi ìyìn fún un,
oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
4 Ẹ fi ìyìn fún un,
ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.
5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
àti ẹ̀yin ibú Òkun
8 Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
9 Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.
13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Orúkọ Sioni tuntun
62 Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́,
nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu,
títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,
àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.
2 (A)Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ,
àti gbogbo ọba ògo rẹ
a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn
èyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un.
3 Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,
adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
4 Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́
tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.
Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba,
àti ilẹ̀ rẹ ní Beula;
nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ
àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
5 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó
Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.
10 Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!
Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.
Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó!
Ẹ ṣa òkúta kúrò
Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè.
11 Olúwa ti ṣe ìkéde
títí dé òpin ilẹ̀ ayé:
“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
‘kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!
Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,
àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”
12 A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,
ẹni ìràpadà Olúwa;
a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,
Ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.
Ẹni tó gun ẹṣin funfun
11 (A)Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 (B)Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 (C)Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 (D)Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:
Ìtàn ibí Jesu Kristi
18 (A)Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. 19 Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.
20 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. 21 (B)Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
22 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: 23 (C)“Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”
24 Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. 25 Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.