Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 37

Ti Dafidi.

37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
    kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
    wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.

Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
    torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
    òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.

Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
    gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
    àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
    kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
    nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.

Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
    má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
    ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
    nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
    wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
    wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
    nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.

14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
    wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
    láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
    àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.

16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
    sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
    àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
    àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.

20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
    Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
    wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.

21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
    ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
    àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.

23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
    o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
    nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.

25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
    síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
    tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
    a sì máa bùsi i fún ni.

27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
    nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
    kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
    ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
    yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
    àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
    Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
    nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

34 Dúró de Olúwa,
    kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
    nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
    ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
    bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.

37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
    nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
    ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.

39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
    òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
    yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
    nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

Deuteronomi 4:32-40

Olúwa ni Ọlọ́run

32 Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí? 33 Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè? 34 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnrarẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ ààmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?

35 A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀. 36 Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá, 37 torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti. 38 Láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.

39 Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́. 40 Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.

2 Kọrinti 3

(A)Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe? Ẹ̀yin fúnrayín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. (B)Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.

Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run: Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà; Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.

Ògo tó wà nínú májẹ̀mú tuntun

(C)Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (D)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

Luku 16:1-9

Òwe ọlọ́gbọ́n òṣìṣẹ́

16 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’

“Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe. Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’

“Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’

“Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n òróró.’

“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’

“Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ?’

“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n alikama.’

“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’

(A)“Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. (B)Èmi sì wí fún yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí o ba lọ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.