Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 88

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.

88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
    ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
    dẹ etí rẹ sí igbe mi.

Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
    ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
    èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
    bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
    ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
    ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
    ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
    ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.

    Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
    Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
    Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
    àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?

13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
    ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
    tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
    èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
    èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
    ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
    wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
    òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

Saamu 91-92

91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
    “Òun ni ààbò àti odi mi,
    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
    ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
    ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
    Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
    aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú
    bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe
    búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
    nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
    ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
    òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
    ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
    tí ó dìde sí mi.

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”

Isaiah 61:1-9

Ọdún ojúrere Olúwa

61 (A)Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi
    nítorí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn mí
láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà.
    Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
    àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa
    àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
    láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
    láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
    àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
    irúgbìn Olúwa
    láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́
    wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;
wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà
    tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.
Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;
    àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,
    a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
    àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

Dípò àbùkù wọn
    àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
àti dípò àbùkù wọn
    wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
    ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.

“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;
    mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀
Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn
    èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé
    wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”

2 Timotiu 3

Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn

Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. (A)Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu

10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11 (B)Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 16 Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. 17 Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.

Marku 10:32-45

Jesu tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀

32 (A)Nísinsin yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerusalẹmu. Jesu sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn. 33 (B)Ó sọ fún wọn pé, “Àwa ń gòkè lọ Jerusalẹmu, a ó sì fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà. 34 (C)Wọn yóò fi ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàṣán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.”

Ìbéèrè Johanu àti Jakọbu

35 (D)Lẹ́yìn èyí, Jakọbu àti Johanu, àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.”

36 Jesu béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?”

37 (E)Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnìkejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ!”

38 (F)Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitiisi yín pẹ̀lú irú ì bamitiisi ìjìyà tí a ó fi bamitiisi mi?”

39 (G)Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.”

Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitiisi tí a sí bamitiisi mi ni a ó fi bamitiisi yín, 40 ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún.”

41 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú. 42 (H)Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn. 43 (I)Ṣùgbọ́n láàrín yín ko gbọdọ̀ ri bẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́. 44 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín. 45 (J)Nítorí, Èmi, Ọmọ Ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ṣe ìránṣẹ́ fun àwọn ẹlòmíràn, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.