Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
37 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;
torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;
òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
5 Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;
gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,
kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
a sì máa bùsi i fún ni.
27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
34 Dúró de Olúwa,
kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn;
yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,
Èmi yóò fún ọ ní okun,
bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn
títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀
kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn
mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù;
Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
Èmi Olúwa ni ó ti dá a.
9 (A)“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
‘Òun kò ní ọwọ́?’
10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,
‘Kí ni o bí?’
tàbí sí ìyá rẹ̀,
‘Kí ni ìwọ ti bí?’
11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí
Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀:
Nípa ohun tí ó ń bọ̀,
ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,
tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé
tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.
Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run
mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta
13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi:
Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.
Òun yóò tún ìlú mi kọ́
yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
14 (B)Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,
àti àwọn Sabeani—
wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;
wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,
wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,
wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,
‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;
kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,
Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli
16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì
wọn yóò sì kan àbùkù;
gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
17 (C)Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa
pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;
a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,
títí ayé àìnípẹ̀kun.
15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16 (A)Ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19 (B)Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.
Àwọn aya àti ọkọ
21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
22 (C)Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. 23 Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. 24 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.
25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. 26 Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. 27 Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. 28 Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnrawọn. 29 Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. 30 Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. 31 (D)Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. 32 Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. 33 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Àtùpà lórí ọ̀pá fìtílà
21 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òṣùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22 (B)Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23 (C)Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 (D)Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. 25 (E)Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”
Òwe irúgbìn tó ń dàgbà
26 (F)Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”
Òwe musitadi
30 (G)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (H)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.