Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
2 Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
3 Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.
4 Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
5 Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
6 Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,
Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
8 Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
9 Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.
10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.
87 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
2 Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni
ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.
3 Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,
ìlú Ọlọ́run;
4 “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli
láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:
Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi
yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
5 Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,
“Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,
àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
6 Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:
“Eléyìí ni a bí ní Sioni.”
7 Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu
ohun èlò orin yóò wí pé,
“Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”
Maskili ti Etani ará Esra.
89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
3 (A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13 Ìwọ ní apá agbára;
agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé:
“Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20 (B)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 (C)Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
Mose àti igbó tí ń jó
3 (A)Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. 2 (B)Níbẹ̀ ni angẹli Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run 3 Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”
4 Nígbà tí Olúwa rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!”
Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”
5 (C)Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.” 6 (D)Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.
7 Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. 8 Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. 9 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. 10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”
11 Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?”
12 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”
23 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Mose pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí tiwọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.
24 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; 25 o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 26 Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà. 27 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí. 28 (D)Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrékọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má bá a fi ọwọ́ kan wọn.
29 (E)Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la Òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.
30 (F)Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jeriko wo lulẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ọjọ́ méje.
31 (G)Nípa ìgbàgbọ́ ni Rahabu panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́rọ̀ nígbà tí o tẹ́wọ́gbà àwọn ààmì ní àlàáfíà.
6 (A)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. 7 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
8 Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”
9 (B)Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba: Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ 10 Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 11 (C)Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi: bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá! 12 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba. 13 (D)Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ. 14 Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.