Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé
18 (A)Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
2 Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
3 Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
4 Ìrora ikú yí mi kà,
àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
5 Okùn isà òkú yí mi ká,
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
6 Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;
Mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
7 Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
8 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
9 Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;
àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10 Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;
ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11 Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká
kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
12 Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
13 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;
Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15 A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn Òkun hàn,
a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
nípa ìbáwí rẹ, Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
16 Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
17 Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
18 Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;
ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
19 Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;
Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
20 Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi
21 Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́;
èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
22 Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
23 Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;
mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24 Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
25 Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,
sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26 Sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,
ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27 O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28 Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi
kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
29 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;
pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,
a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa
òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?
Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè
ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;
ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34 Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà;
apá mi lè tẹ ọrùn idẹ
35 Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;
àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,
kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
37 Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn
èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38 Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;
Wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;
ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi
40 Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi
èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,
àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
42 Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;
mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
43 Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;
Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
44 ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;
àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
45 Àyà yóò pá àlejò;
wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
46 Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!
Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
47 Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,
tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
48 tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.
Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
49 (B)Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa;
Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
50 Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;
ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀,
fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.
Orin ìyìn
12 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé:
“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú.
2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
òun ti di ìgbàlà mi.”
3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
láti inú kànga ìgbàlà.
4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:
“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
kí o sì kéde pé a ti gbé
orúkọ rẹ̀ ga.
5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
ti Israẹli láàrín yín.”
Ọ̀rọ̀ ìṣáájú
1 Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀: 2 Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. 3 Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ìkíni àti ìyìn
4 (A)Johanu,
Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia:
Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; 5 (B)àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.
Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, 6 (C)tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.
7 (D)Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;
gbogbo ojú ni yóò sì rí i,
àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;
àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.
8 (E) “Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”
37 (A)Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. 38 (B)Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” 39 (C)(Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.)
40 (D)Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”
41 Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.”
Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí? 42 (E)Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?” 43 Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀. 44 (F)Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.
Àìgbàgbọ́ àwọn adarí Júù
45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”
46 (G)Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”
47 Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí? 48 Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí? 49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”
50 (H)Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, 51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”
52 (I)Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.