Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
28 Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi;
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
6 Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
Ìwà búburú Joaṣi
17 Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn. 18 Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí Juda àti Jerusalẹmu. 19 Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.
20 Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Sekariah ọmọ Jehoiada wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ Olúwa? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ Olúwa sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”
21 Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé Olúwa 22 Ọba Joaṣi kò rántí inú rere tí Jehoiada baba Ṣakariah ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.”
Yíyan àwọn méje
6 Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́. 2 Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. 3 Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. 4 Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”
5 Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku. 6 Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.
7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.
118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
3 Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”
5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,
ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
6 (B)Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi
Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.
8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,
ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò
11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù
12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,
ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;
ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
14 Olúwa ni agbára àti orin mi;
ó sì di ìgbàlà mi.
15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:
“Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;
ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,
èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
18 Olúwa bá mi wí gidigidi,
ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
ìwọ sì di ìgbàlà mi.
22 (C)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
25 (D)Olúwa, gbà wá;
Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.
Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
27 Olúwa ni Ọlọ́run,
ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
59 Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60 Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.
8 (A)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká
Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. 2 Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
Filipi ní Samaria
4 Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. 5 Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. 6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ ààmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. 7 Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. 8 Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.