Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 89:1-29

Maskili ti Etani ará Esra.

89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
    pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
    pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
(A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
    mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
    èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
    òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
    Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
    ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
    ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.

Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
    nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
    bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
    tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
    ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
    Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13 Ìwọ ní apá agbára;
    agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
    ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
    Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
    wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
    nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
    ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé:
    “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
    èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20 (B)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
    pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
    apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
    àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
    èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
    àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
    àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 (C)Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
    Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
    àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
    àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

Isaiah 59:15-21

15 A kò rí òtítọ́ mọ́,
    àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.

Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́
    pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,
    àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;
nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,
    àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
17 (A)Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,
    àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;
ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀
    ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,
    bẹ́ẹ̀ ni yóò san án
ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀
    àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
    òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
19 (B)Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
    àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.
Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi
    èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.

20 (C)“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,
    sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó
    ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni Olúwa wí.

Filipi 2:5-11

(A)Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.

Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,
    kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,
    ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,
    a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,
    ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,
    o sì tẹríba títí de ojú ikú,
        àní ikú lórí àgbélébùú.

(B)Nítorí náà, Ọlọ́run
    ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,
    ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un
10 Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,
    ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
11 Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,
    fún ògo Ọlọ́run Baba.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.