Book of Common Prayer
Òfin Ọlọ́run ní ìrètí
49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,
èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 nítorí tí mo
gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
Ọlọ́run ni ìpín wa
57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ Olúwa
Kọ́ mi ní òfin rẹ.
Ìpọ́njú mu ni mọ òfin Ọlọ́run
65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
4 Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
5 Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
6 Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
7 Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
9 Ní ti kí ó máa wà títí ayé
láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
gbàgbọ́ nínú ara wọn,
àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú
ikú yóò jẹun lórí wọn;
ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,
jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀;
Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,
isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
kúrò nínú isà òkú,
yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú
18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí mahalati. Maskili ti Dafidi.
53 (A)(B) Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé:
“Ọlọ́run kò sí.”
Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;
kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere.
2 Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run
sórí àwọn ọmọ ènìyàn,
láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,
tí ó sì ń wá Ọlọ́run.
3 Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,
wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;
kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
4 Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?
Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun
tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?
5 Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá
níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí,
nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká;
ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.
6 Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni!
Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!
Ìbínú Olúwa Sí Israẹli
8 Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
Yóò sì wá sórí Israẹli.
9 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—
tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga
àti gààrù àyà pé.
10 Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,
a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀
ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
11 Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.
12 Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run.
Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
Ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.
13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
14 Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
kúrò ní Israẹli,
àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,
15 Àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà
Àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.
Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
Àwọn olùkọ́ni èké àti ìparun wọn
2 (A)Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 3 Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.
4 Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. 5 (B)Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. 6 (C)Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 (D)Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; 8 (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́) 9 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 10 Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè.
Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.
Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀
1 Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
2 (A)(B) Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé:
“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
3 (C)“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
4 (D)Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. 5 Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 6 Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. 7 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. 8 Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.