Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
Ti Dafidi.
28 Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi;
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
6 Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa
36 (A)Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú
jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé;
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí
níwájú wọn.
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:
a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.
39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
2 Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
3 Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4 “Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
5 Ìwọ ti ṣe ayé mi
bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6 “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
9 Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
13 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò
lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ
yóò sì gbẹ.
14 Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.
15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
24 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run
àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,
bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà
tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:
nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀
wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
25 Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀,
ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.
Àwọn òkè sì wárìrì,
òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò,
ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn
12 (A)Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa. 13 (B)Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ní àlàáfíà láàrín ara yín. 14 (C)Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 15 (D)Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.
16 (E)Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo 17 (F)Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo 18 (G)Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.
19 (H)Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́. 20 (I)Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń sọtẹ́lẹ̀. 21 (J)Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú. 22 Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.
23 (K)Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa. 24 Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.
25 Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.
26 (L)Ẹ fi ìfẹ́nukonu mímọ́ ki ara yin.
27 (M)Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.
28 (N)Ki oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín.
29 (A)Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi; 30 Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.
32 (B)“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. 33 (C)Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.
34 (D)“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. 35 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. 36 (E)Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”
37 (F)Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili: lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. 38 Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.