Book of Common Prayer
Ti Dafidi.
25 Olúwa,
ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́
ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
ni kí ojú kí ó tì.
4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
kọ mi ní ipa tìrẹ;
5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;
nítorí pé mo dúró tì ọ́.
22 Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run,
nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
Fún adarí orin. Ní ti ohun orin “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.
9 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3 Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
5 Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.
7 Olúwa jẹ ọba títí láé;
ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8 (A)Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.
Saamu ti Dafidi
15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédé
tí ó sì ń sọ òtítọ́,
láti inú ọkàn rẹ̀;
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
ni a kì yóò mì láéláé.
Ègún àti ìdájọ́
8 Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé
tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀
tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù
tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.
9 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:
“Ó dájú pé àwọn ilé ńláńlá
yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.
10 Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
ìkòkò wáìnì kan wá,
nígbà tí òṣùwọ̀n homeri kan yóò mú
agbọ̀n irúgbìn kan wá.”
11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
ní kùtùkùtù òwúrọ̀
láti lépa ọtí líle,
tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
12 Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
18 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,
àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
19 sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,
jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,
jẹ́ kí ó súnmọ́ bí
jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,
kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
20 Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,
tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,
tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn
tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
22 Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu
àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.
5 (A)Nísinsin yìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà, 2 (B)nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru. 3 (C)Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.
4 (D)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè. 5 (E)Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́. 6 (F)Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́. 7 (G)Nítorí àwọn tí wọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru. 8 (H)Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí ìgbàyà ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí àṣíborí. 9 (I)Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi. 10 Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 11 Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.
20 (A)“Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. 21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 23 (B)Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 24 (C)Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.
25 (D)(E) “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27 (F)Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28 (G)Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.