Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 120-127

Orin fún ìgòkè.

120 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,
    ó sì dá mi lóhùn
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
    àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

Kí ni kí a fi fún ọ?
    Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
    pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.

Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
    nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kedari!
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
    láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
    ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

Orin fún ìgòkè.

121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
    yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
    Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
    ìwọ Jerusalẹmu.

Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
    tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
    àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
    máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
    àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.

Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
    àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
    àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
    èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
    kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
    èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

Orin fún ìgòkè.

123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
    ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
Kíyèsi, bí ojú àwọn
    ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
    àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
    títí yóò fi ṣàánú fún wa.

Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
    nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
Ọkàn wa kún púpọ̀
    fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
    àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

124 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
    ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
    Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
    nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
Nígbà náà ni omi
    wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.

Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
    bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
    okùn já àwa sì yọ.
Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
    tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Orin fún ìgòkè.

125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
    kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
    fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
    àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
    Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
    àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
    bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
    láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
    bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
    ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
    ojú kì yóò tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

Sekariah 11:4-17

Olùṣọ́-àgùntàn méjì

Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni Olúwa wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”

Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà. Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan.

Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi. Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”

10 Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá. 11 Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni.

12 (A)Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.

13 Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.

14 Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli.

15 Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀. 16 Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dìde ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyí tí ó ni ọ̀rá, àwọn èyí tiwọn fi èékánná wọn ya ara wọn pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

17 “Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn asán náà,
    tí ó fi ọ̀wọ́ ẹran sílẹ̀!
Idà yóò gé apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀:
    apá rẹ̀ yóò gbẹ pátápátá,
    ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátápátá!”

1 Kọrinti 3:10-23

10 (A)Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. 11 (B)Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. 12 Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 13 (C)Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14 Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. 15 (D)Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.

16 (E)Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? 17 Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹmpili Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹmpili Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yin jẹ́.

18 (F)Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. 19 (G)Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; 20 (H)lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” 21 (I)Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo. 22 (J)Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn. 23 Ẹ̀yin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọ́run.

Luku 18:31-43

Jesu tún sọ nípa ikú rẹ̀

31 (A)Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn. 32 Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára. 33 Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á: ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”

34 Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn: ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.

Afọ́jú alágbe gba ìwòsàn

35 (B)Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe: 36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí. 37 Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”

38 Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

39 Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

40 Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, 41 Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”

Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

42 (C)Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” 43 Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.