Book of Common Prayer
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.
88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
dẹ etí rẹ sí igbe mi.
3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
9 Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.
91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
“Òun ni ààbò àti odi mi,
Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
6 Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
7 Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.
9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”
Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi
92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
2 Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
3 Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
àti lára ohun èlò orin haapu.
4 Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
5 Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
6 Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
7 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú
bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe
búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.
8 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
9 Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
tí ó dìde sí mi.
12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
kankan nínú rẹ̀.”
Ọjọ́ Olúwa
28 (A)“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́,
èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo;
àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀,
àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá,
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
29 Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,
àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,
ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.
30 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun
àti ní ayé,
ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.
31 (B)A á sọ oòrùn di òkùnkùn,
àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,
kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.
32 (C)Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè
orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà:
nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu
ní ìgbàlà yóò gbé wà,
bí Olúwa ti wí,
àti nínú àwọn
ìyókù tí Olúwa yóò pè.
A dá orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́
3 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà,
nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.
2 Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ
pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí Àfonífojì Jehoṣafati.
Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,
àti nítorí Israẹli ìní mi,
tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè,
wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.
3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi;
wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,
wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún
ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.
4 (D)“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. 5 Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. 6 Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.
7 “Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. 8 Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.
16 Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. 17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. 18 Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.
Gbígbọ́ àti ṣíṣe ọrọ̀ náà
19 Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; 20 Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́. 21 Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.
22 Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ. 23 Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí 24 Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí. 25 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.
26 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán. 27 Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìní baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò nínú ayé.
Òwe ọlọ́gbọ́n òṣìṣẹ́
16 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. 2 Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’
3 “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe. 4 Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’
5 “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’
6 “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n òróró.’
“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’
7 “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ?’
“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n alikama.’
“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’
8 (A)“Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. 9 (B)Èmi sì wí fún yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí o ba lọ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.