Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 70-71

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
    ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
    àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
    lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
    nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
    wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
    bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
    èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
    Olúwa Olódùmarè;
    èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
    títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
    àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
    ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
    Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
    ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
    láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
    ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
    fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
    ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
    nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
    èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
    fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
    a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Saamu 74

Maskili ti Asafu.

74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
    Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
    ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
    Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
    gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.

Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
    láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
    láti gé igi igbó dídí.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
    ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
    wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
    Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
    kò sí wòlíì kankan
    ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
    Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
    Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!

12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
    Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
    Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
    Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
    ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
    Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
    Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
    bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
    Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
    nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
    jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
    rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
    bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.

Error: Book name not found: Sir for the version: Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìfihàn 16:12-21

12 (A)Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Eufurate; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèsè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà-oòrùn wá. 13 (B)Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dragoni náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá. 14 Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.

15 (C)“Kíyèsi i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó má bá a rìn ni ìhòhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”

16 (D)Ó sì gbá wọn jọ́ sí ibìkan tí a ń pè ní Amagedoni ní èdè Heberu.

17 (E)Èkeje si tú ago tirẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹmpili jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!” 18 (F)Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀. 19 Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un. 20 Olúkúlùkù erékùṣù sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́. 21 (G)Yìnyín ńlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó tálẹ́ǹtì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.

Luku 13:18-30

Òwe irúgbìn tó kéré jùlọ àti ohun tí n mú ìyẹ̀fun wú

18 (A)Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? 19 Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”

20 (B)Ó sì tún wí pé, “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé? 21 Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”

Ọ̀nà tóóró

22 (C)Ó sì ń la àárín ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọ́ni, ó sì ń rìn lọ sí Jerusalẹmu. 23 (D)Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha kọ ni àwọn tí a ó gbàlà?

Ó sì wí fún wọn pé, 24 “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé. 25 (E)Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’

“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín.

26 (F)“Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú wa.’

27 “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

28 (G)“Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde. 29 Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run. 30 (H)Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.