Book of Common Prayer
Maskili ti Etani ará Esra.
89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
3 (A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13 Ìwọ ní apá agbára;
agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé:
“Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20 (B)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 (C)Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀
tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́
tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
32 Nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;
àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán:
33 Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;
èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,
àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
37 (D)A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,
àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”. Sela.
38 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra;
ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni ààmì òróró rẹ.
39 Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo;
ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku
40 Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀
ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
41 Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;
ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè;
ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.
43 Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà,
ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
44 Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà,
ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
45 Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;
ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.
46 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?
Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé?
Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó
nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
48 Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?
Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?
49 Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,
tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
50 Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
51 Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa,
tí wọn gan ipasẹ̀ Ẹni ààmì òróró rẹ.
52 Olùbùkún ní Olúwa títí láé.
Àmín àti Àmín.
14 “Nítorí náà, èmi yóò tàn án
Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀
Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀
15 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.
16 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,
Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’;
Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’
ni Olúwa wí.
17 Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀;
ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́
18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú
fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti
àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.
Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́
Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà
kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
19 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé.
Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti
òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
20 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́
ìwọ yóò sì mọ Olúwa.
21 “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà”
ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn
àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
22 Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,
wáìnì tuntun àti òróró lóhùn
Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
23 Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà
Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àánú Gbà.’
Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’
‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”
17 Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 18 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà. 19 Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù: 20 Bí èmí kò ti fàsẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. 21 Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Giriki pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi Olúwa wa.
22 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerusalẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀: 23 Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi. 24 Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrín ẹni tí èmi tí ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́. 26 Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo. 27 Nítorí tí èmi kò fàsẹ́yìn láti sọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin. 28 Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà. 29 Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín, yóò sì tú agbo ká. 30 Láàrín ẹ̀yin tìkára yín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn. 31 Nítorí náà ẹ máa ṣọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.
32 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́. 33 Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni. 34 Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. 35 Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”
36 Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà. 37 Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 38 Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.
Ìpè àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
5 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti. 2 Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. 3 (B)Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.
4 Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”
5 (C)Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”
6 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. 7 Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.
8 Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” 9 Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó: 10 Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni.
Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” 11 Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.