Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:49-72

Òfin Ọlọ́run ní ìrètí

49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
    ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
    ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,
    èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
    tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
    níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,
    èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 nítorí tí mo
    gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.

Ọlọ́run ni ìpín wa

57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:
    èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
    fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
    èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
    láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
    èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
    nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
    sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ Olúwa
    Kọ́ mi ní òfin rẹ.

Ìpọ́njú mu ni mọ òfin Ọlọ́run

65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
    gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
    nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
    ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
    kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
    èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
    ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
    nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
    ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.

Saamu 49

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
    Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
    tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
    èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
    Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
    tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
    padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
    kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
Ní ti kí ó máa wà títí ayé
    láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
    bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
    ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
    ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
    gbàgbọ́ nínú ara wọn,
àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
    tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú
    ikú yóò jẹun lórí wọn;
ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,
    jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀;
Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,
    isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
    kúrò nínú isà òkú,
yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
    Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
    ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú
18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
    Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
    àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Saamu 53

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí mahalati. Maskili ti Dafidi.

53 (A)(B) Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé:
    “Ọlọ́run kò sí.”
Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;
    kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere.

Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run
    sórí àwọn ọmọ ènìyàn,
láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,
    tí ó sì ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,
    wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;
kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?

    Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun
    tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?
Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá
    níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí,
nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká;
    ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.

Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni!
    Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
    jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!

Oniwaasu 3:1-15

Àkókò àti ìgbà wà fún ohun gbogbo

Àsìkò wà fún ohun gbogbo,
    àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.

Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,
    ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.
Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá
    ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.
Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín
    ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó
Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ
    ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn
Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri
    ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
Ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán
    ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀
Ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra
ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.

Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀? 10 Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn. 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. 12 Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè. 13 Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́. 14 Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.

15 Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀,
    ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀,
    Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀.

Galatia 2:11-21

Paulu tako Peteru

11 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.

14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?

15 “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’ 16 (B)Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18 Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin.

19 “Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. 20 (C)A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. 21 Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

Matiu 14:1-12

A bẹ́ Johanu Onítẹ̀bọmi lórí

14 (A)Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”

(B)Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” (C)Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.

Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. 10 Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. 11 A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.