Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.
45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
3 Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ
wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
4 Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà
lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
5 Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
6 (A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà ofiri.
10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
wọ́n sì wọ ààfin ọba.
16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.
48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2 (A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
ní ìlú ọba ńlá.
3 Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4 Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
5 Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
6 Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
7 Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ní ìlú Ọlọ́run wa,
Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.
9 Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
nítorí ìdájọ́ rẹ.
12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
14 Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.
Ìpè méje
15 (A)Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,
“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;
òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”
16 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17 wí pé:
“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,
tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,
nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,
ìwọ sì ti jẹ ọba.
18 (B)Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé,
àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,
àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,
àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,
àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;
àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”
19 (C)A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
27 (A)Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”
28 Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”
Ààmì ti Jona
29 (B)(C) Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí: wọ́n ń wá ààmì; a kì yóò sì fi ààmì kan fún un bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì! 30 Nítorí bí Jona ti jẹ́ ààmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ ènìyàn yóò ṣe jẹ́ ààmì fún ìran yìí. 31 (D)Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí. 32 (E)Àwọn ará Ninefe yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona; sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Jona lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.
Òwe nípa fìtílà tí a tàn
33 (F)“Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé ba à lè máa rí ìmọ́lẹ̀. 34 (G)Ojú ni fìtílà ara: bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn. 35 Nítorí náà kíyèsi i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn. 36 Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apá kan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.