Book of Common Prayer
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
Saamu 1–41
1 (A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
2 (B)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
sí Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò
lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
7 (C)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:
Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí, èmi ti di baba rẹ.
8 (D)Béèrè lọ́wọ́ mi,
Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
3 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.
4 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
ìwọ Ọlọ́run òdodo mi,
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4 (E)Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;
Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5 Ẹ rú ẹbọ òdodo
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
Olúwa, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o
mú mi gbé láìléwu.
Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.
7 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
5 Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.
6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
Jọba lórí wọn láti òkè wá;
8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
9 (A)Ọlọ́run Olódodo,
Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.
Àwọn ẹ̀yà ìkọjá odò Jordani
32 Àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilẹ̀ Jaseri àti Gileadi dára fún ohun ọ̀sìn. 2 Àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni sì wá, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé, 3 “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni. 4 Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú ìjọ Israẹli tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn. 5 Tí a bá rí ojúrere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má ṣe jẹ́ kí a rékọjá odò Jordani.”
6 Mose sọ fún àwọn ọmọ Gadi àti fún ọmọ Reubeni pé, “Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókòó sí bí?
16 Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhìn-ín yìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa. 17 Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdáàbòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà. 18 A kì yóò padà sí ilẹ̀ wa láìṣe pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti gba ogún wọn. 19 A kì yóò gba ogún kankan pẹ̀lú wọn ní òdìkejì Jordani, nítorí ogún ti wa, ti wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani.”
20 Nígbà náà ni Mose sọ fún wọn pé, “Tí ẹ̀yin yóò bá pa ara yín lára, níwájú Olúwa fún ogún. 21 Bí gbogbo yín yóò bá lọ sí Jordani ní ìhámọ́ra níwájú Olúwa, títí yóò fi lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀. 22 Tí a ó sì fi ṣe ilẹ̀ náà níwájú Olúwa; ẹ̀yin lè padà tí yóò sì di òmìnira lọ́wọ́ ìdè níwájú Olúwa àti Israẹli. Ilẹ̀ yìí yóò sì jẹ́ tiyín níwájú Olúwa.
23 “Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kọ̀ láti ṣe èyí, ẹ̀yin yóò máa dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa; kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ dájú pé ẹ̀ṣẹ̀ yín yóò fi yín hàn. 24 Ẹ kọ́ ilé fún àwọn obìnrin yín àti ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àti ilé fún agbo ẹran yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó ṣe ohun tí ẹ ti pinnu.”
25 Àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni sọ fún Mose pé, “Àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti pàṣẹ. 26 Àwọn ọmọ wa àti ìyàwó wa, àwọn agbo ẹran àti ohun ọ̀sìn wa yóò dúró ní ìlú Gileadi. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra ogun, yóò rékọjá lọ láti jà níwájú Olúwa; gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti sọ.”
26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27 (A)Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.
28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29 (B)Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀ 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.
Ìdí méje fún ìdájọ́
23 Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 2 “Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, 3 Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. 4 Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an.
5 (A)“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. 6 Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. 7 Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’
8 (B)“Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. 9 Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 10 Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. 12 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.