Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
140 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,
yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì;
2 Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;
nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,
oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì
ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú
5 Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:
wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;
wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
6 Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;
Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
8 Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
Má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.
9 Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:
Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,
yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà
13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò
máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;
àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.
Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.
142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
6 Fi etí sí igbe mi,
nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
Saamu ti Dafidi.
141 Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.
Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí
àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
3 Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:
kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,
Láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú
má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
5 Jẹ́ kí olódodo lù mí: ìṣeun ni ó jẹ́:
jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.
Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.
Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú
6 A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,
àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
7 Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”
8 Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè;
nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
9 Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,
kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,
nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.
Saamu ti Dafidi.
143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
fetísí igbe mi fún àánú;
nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
2 (A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
3 Ọ̀tá ń lépa mi,
ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.
7 Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
24 Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. 2 Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ 3 ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:
“Ó wí pé Balaamu ọmọ Beori,
òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,
4 Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:
5 “Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,
àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!
6 “Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
7 Omi yóò sàn láti inú garawa:
èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;
ìjọba wọn yóò di gbígbéga.
8 “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.
9 (A)Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,
bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?
“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,
kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”
10 Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. 11 Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”
12 Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13 ‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?
12 Nítorí náà ará a ni ojúṣe láti ṣe, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa nǹkan tí ara, tí a ó fi máa gbé nípa ti ara. 13 (A)Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì ṣègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ń gbé nípa ti ara, ẹ̀yin yóò kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yín bá ń gbé nípa ti Ẹ̀mí, ẹ ó pa iṣẹ́ ti ara run, ẹ̀yin yóò yè.
14 (B)Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. 15 (C)Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” 16 (D)Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. 17 (E)Níwọ́n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ajogún ni àwa, ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bí ó bá ṣe àwa jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.
Sísan owó orí fún Kesari
15 (A)(B) Nígbà náà ni àwọn Farisi péjọpọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un. 16 Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olóòtítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 17 Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?”
18 Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? 19 Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, 20 ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?”
21 (C)Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.”
“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.